Awọn to fẹẹ gba gareeji lo fa ijaagboro to ṣẹlẹ l’Ọbalende-Jimoh

Faith Adebọla, Eko

Inu idarudapọ lawọn eeyan agbegbe Ọbalende ji si laaarọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee yii, pẹlu bi iro ibọn ṣe n dun lakọlakọ, tawọn ero to fẹẹ lọọ wọ mọto atawọn to n lọ ṣenu ọrọ aje wọn ni lati sa asala fẹmi-in wọn.

Ko kọkọ sẹni to mọ ohun to fa laasigbo ati idarudapọ ọhun, tawọn eeyan bẹrẹ si i sa kijokijo loke ati isalẹ biriiji Ọbalende, ṣugbọn Ọgbẹni Jimọh Buhari to jẹ agbẹnusọ fun alaga ẹgbẹ onimọto NURTW, Musiliu Ayinde Akinsanya (MC Oluọmọ), sọ f’ALAROYE pe ija laarin awọn ẹgbẹ onimọto meji nija ọhun, o lawọn ẹgbẹ keji to fẹẹ gba gareeji Ọbalende mọ awọn lọwọ lo da wahala silẹ.

Jimọh ni ẹgbẹ onimọto mẹta lo wa nipinlẹ Eko, ṣugbọn meji lo gbawaju ninu wọn, iyẹn National Union of Road Transport Workers (National) tawọn oṣiṣẹ wọn maa n wọ ẹwu funfun pẹlu ṣokoto olomi ewe. Ẹgbẹ keji ni Road Employers’ Association of Nigeria (Road) tawọn oṣiṣẹ wọn maa n wọṣọ yẹlo. O ni ẹgbẹ mejeeji ti pin gbogbo gareeji ọkọ nipinlẹ naa laarin ara wọn, kaluku lo si ti mọ gareeji ti iṣakoso rẹ de ateyi ti ko de.

O ni lati bii ọsẹ kan sẹyin lawọn ọmọ ẹgbe Road ti n ṣakọlu sawọn oṣiṣẹ National ti wọn n ṣakoso gareeji Ọbalende, wọn lawọn fẹẹ gba gareeji naa mọ wọn lọwọ, ara akọlu naa leyi to waye laaarọ Ọjọbọ yii.

A gbọ pe wahala naa fa sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ gidi fawọn onimọto pẹlu bawọn awakọ kan ati ero ṣe fi mọto wọn silẹ loju popo, ti wọn si sa asala fẹmii wọn.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi, fidi ọrọ yii mulẹ ninu ọrọ to kọ sori atẹ Wasaapu rẹ, o lọwọ awọn ọlopaa ti tẹ janduku meji, awọn bii mẹrin lo ṣeṣe ti wọn gbe lọọ sileewosan, awọn si ti bomi pana rogbodiyan naa, awọn eeyan ti n lọ sẹnu ọrọ-aje wọn lai si wahala kan.

O lawọn agbofinro ti wa nitosi lati fi pampẹ ofin mu ẹnikẹni to ba fẹẹ da omi alaafia ilu naa ru.

Akoroyin wa pe alaga ẹgbẹ Road, Alaaji Musa Mohammed, lori aago rẹ lati gbọ alaye wọn lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn wọn ko gbe ipe naa titi ta a fi ko iroyin yii jọ.

Leave a Reply