Lasiko ti Atẹrẹ n gbe ọmọ rẹ to n saisan lọ sọsibitu ni wọn ji i gbe n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Awọn ajinigbe ti wọn to mẹfa to ji baale ile ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta kan, Alhaji Musa Garba Atẹrẹ, gbe niluu Ilọrin ti kan si mọlẹbi rẹ lati beere fun miliọnu ọgbọn naira owo iyọlọfin rẹ.

Atẹrẹ toun pẹlu iyawo ati ọmọbinrin rẹ kan to n ṣe aarẹ n lọ silewosan ko sọwọ awọn ajinigbe ni nnkan bii aago mẹfa aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lọna Ogundele si Madi, nijọba ibilẹ Ilọrin West.

Iyawo ọkunrin naa ti ko fẹ ka darukọ oun ṣalaye pe awọn ajinigbe naa ni dandan, awọn gbọdọ lọọ wa owo naa ko too di pe wọn le yọnda ọkọ oun.

Nigba to n sọ bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ, obinrin yii ni ṣadeede lawọn ajinigbe naa da awọn lọna, ti wọn si beere fun owo lọwọ awọn.

O ni gbogbo owo to wa lọwọ awọn ati dukia mi-in lawọn ko fun wọn ki wọn le baa fi awọn silẹ, sibẹ, wọn wọ ọkọ oun tuurutu wọ inu igbo lọ.

O ni oju kan naa toun duro si loun ti n wo wọn bi wọn ṣe n wọ ọ, ṣugbọn ko si ẹnikẹni nitosi lati ran awọn lọwọ.

Titi di bi a ṣe n kọ iroyin yii ko sẹni to mọ pato ibi ti wọn gbe ọkunrin naa lọ. Awọn ẹbi naa ni awọn ti fi iṣẹlẹ ọhun to agọ ọlọpaa to wa lagbegbe Adewọle, niluu Ilọrin, leti fun iwadi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ni iwadi ti n lọ lori ẹ.

Leave a Reply