Awọn to ji ọba Ilẹmẹṣọ-Ekiti gbe beere fun miliọnu lọna ogun

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn ajinigbe to ji Ọbadu ti Ilẹmẹṣọ-Ekiti, Ọba David Oyewumi, ti beere fun ogun miliọnu naira lẹyin bii ọjọ mẹrin ti wọn gbe e lọ.

Nnkan bii aago mẹjọ aabọ Ọjọruu, Tọsidee, to kọja lawọn agbebọn naa fo fẹnsi aafin wọle lẹyin tawọn oloye ti wọn waa ṣepade ti lọ sile, bẹẹ ni wọn da ibọn bolẹ lati ko awọn ti wọn ba nibẹ ni papamọra. Lẹyin eyi ni wọn bẹrẹ si i beere ọba alaye naa, ti wọn si n fiya jẹ awọn ti wọn ri, eyi to tumọ si pe oun gan-an ni wọn n wa.

Bi wọn ṣe ri kabiyesi la gbọ pe wọn gbe e, wọn si wọ ọ kuro laafin lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ di akoko yii.

Lasiko naa ni ASP Sunday Abutu to jẹ Alukoro ọlọpaa Ekiti sọ pe nnkan to ba ni lọkan jẹ gbaa niṣẹlẹ, ati pe ibọn tawọn eeyan ọhun fi waa ṣọṣẹ lagbara pupọ.

O waa ni iwadii ti bẹrẹ, ileeṣẹ ọlọpaa yoo si wa gbogbo ọna lati gba Ọba Oyewumi silẹ lọwọ awọn ajinigbe, ati lati mu awọn ọdaran naa.

Ṣugbọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni ẹnikan ninu mọlẹbi kabiyesi naa sọ pe awọn ajinigbe ọhun ti kan si awọn ni nnkan bii go meje alẹ ọjọ Satide to kọja, bẹẹ ni wọn beere fun ogun miliọnu naira ki wọn too le tu baba naa silẹ.

O ni ọrọ naa ti da ibẹru nla silẹ lọkan awọn eeyan kabiyesi, awọn si n gbe igbese ti yoo jẹ ki ọba yii pada lalaafia.

Leave a Reply