Awọn to ji ọga ṣọja gbe l’Ekiti ni ogun miliọnu naira lawọn fẹẹ gba

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn ajinigbe to ji ajagun-fẹyinti kan, Jide Ijadare, gbe nipinlẹ Ekiti lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ti beere fun miliọnu lọna ogun naira ki wọn too le fi i silẹ.

Ijadare lawọn ajinigbe ọhun ko ni ipapamọra nileeṣẹ rẹ ti wọn ti n ṣe epo pupa, to da silẹ soju ọna Ijan-Ekiti si Isẹ-Ekiti.

Bi wọn ṣe ya bo ibudo naa ni wọn yinbọn pa ọkunrin kọngila kan ki wọn too gbe ajagun-fẹyinti to ṣiṣẹ nileeṣẹ ologun ilẹ Amẹrika tẹlẹ naa ati oṣiṣẹ kan.

Ẹnikan to sun mọ mọlẹbi ọkunrin naa sọ pe aarọ ana lawọn ajinigbe ọhun beere fun owo yii.

Bakan naa ni Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe Tunde Mobayọ to jẹ kọmiṣanna ọlọpaa ti ko oriṣiiriṣii ikọ lọ si agbegbe tiṣẹlẹ ọhun ti waye, bẹẹ lo ni kawọn eeyan fọkan balẹ, awọn ti wọn ji gbe yoo pada lalaafia.

Ẹwẹ, awọn adari ẹka to n ṣetọju awọn agunbanirọ nipinlẹ Ekiti ti sọ pe ko si ootọ ninu iroyin to jade lanaa pe agunbanirọ lẹni tawọn ajinigbe naa yinbọn pa.

Abilekọ Mary Nnena Chikezie to jẹ adari ẹka naa lo kede ọrọ naa lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Chikezie ni ko si agunbanirọ kankan to n ṣiṣẹ ni ibudo naa, ko si si eyi ti wọn yinbọn pa, nitori naa, kawọn araalu ma gba iroyin ọhun gbọ rara.

 

 

 

Leave a Reply