Awọn to mọ bọrọ ọmọ Tọpẹ Alabi ṣe jẹ ti sọrọ o, wọn ni Ọlaoye gan-an lo lọmọ, ki i ṣe Sọji Alabi

Titi di ba a ṣe n sọ yii, nnkan ko fi bẹẹ rọrun nile gbajumọ olorin ẹmi nni, Tọpẹ Alabi, pẹlu bi ọkunrin kan ti wọn ni oun naa maa n gbe fiimu jade, Mayegun Ọlaoye ṣe gbe e jade lọsẹ to kọja pe oun loun ni akọbi ọmọ ti Tọpẹ Alabi bi torukọ rẹ n jẹ Ayọmikun.

Ọkunrin naa ni ki i ṣe pe oun loun ni in nikan kọ, oun loun fun un lorukọ, iyẹn Mary Ayọmikun Oyegoke. Ṣugbọn o jẹ ohun ibanujẹ fun oun pe Tọpẹ ko jẹ ki oun ri ọmọ naa, bẹẹ lo tun yi orukọ rẹ pada kuro ni orukọ oun si orukọ ọkọ to ṣẹṣẹ fẹ, iyẹn Alabi.

Nigba ti ALAROYE lọ sori ikanni ọkunrin naa, fọto ọmọbinrin yii kun ori ibẹ, bẹẹ lo si maa n ki ọmọ yii lasiko to ba n sọjọọbi lori ikanni Instagraamu rẹ.

Ninu ọrọ kan to kọ nigba ti ọmọ yii ṣọjọọbi ni ọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun 2018, o ni, ‘Ọla (iyẹn ọjọ keje, oṣu karun-un, 2018) ni yoo pe ogun ọdun geerege ti mo bi ọ. Ile igbẹbi CAC (CAC Merternity Home), to wa ni PWD, Oshodi, la bi ọ si, ayọ si kun inu mi gidigidi nitori pe iwọ ni akọbi mi nile aye. Mo si sọ ọ ni Mary Ayọmikun Oyegoke ni ile mi to wa ni Ṣomolu, lọjọ kẹrinla, oṣu karun-un, ọdun 1998. Ayọmikun, emi ni baba to bi ọ lọmọ, ti ko si si ẹnikẹni to le sọ pe oun loun bi ọ yatọ si mi. Mo ki ọ ku oriire ọjọọbi, akọbi mi, mo nifẹẹ rẹ, titi aye ni n oo si maa nifeẹ rẹ. Mo gbadura pe ki o ṣe aṣeyege laye, ọmọ mi obinrin daadaa.’’

Bo tilẹ jẹ pe oriṣiiriṣii awuyewuye lo ti n waye lori ọrọ yii, awọn to mọdi ọrọ ọhun ti sọ pe Ọlaoye gan-an lo lọmọ, ki i ṣẹ Sọji Alabi, ti Tọpẹ wa lọọdẹ rẹ, wọn ni o gbe e lọọ fe ẹ ni. Tọpẹ paapaa ko si jiyan eleyii, sugbọn ohun to fa wahala ni bi Tọpẹ ṣe yi orukọ ọmọ naa pada, ti ko si tun je ki baba to bi i ni anfaani lati maa ri i gẹgẹ bi ọkunrin naa ṣe sọ.

Ọkan lara awọn to sun mọ ọn awọn mejeeji daadaa nigba ti wọn ṣi wa papọ  to ni ka ma darukọ oun sita sọ fun ALAROYE pe tọkọ-tiyawo ni Tọpẹ Alabi ati Mayegun Ọlaoye, ni nnkan bii ọdun mẹtalelogun sẹyin.

Ọkan lara awọn makẹta to maa n ta fiimu Yoruba ni ọkunrin naa n ṣe, ati pe oun gan-an lo ni ileeṣẹ Olaoye Global Ventures, to wa l’Ekoo. Bẹẹ ni wọn tun ni o maa n ta mọto.

Ẹni to ba wa sọrọ yii sọ pe lọdọ Alade Aromirẹ gan-an ni Tọpẹ Alabi ati Ọgbẹni Ọlaoye yii ti pade, lasiko igba ti gbajumọ olorin ẹmi yii naa fi n ṣe iṣẹ tiata ninu ẹgbẹ oṣere Oriire Caucus, eyi ti i ṣe ti Alade Aromirẹ.

ALAROYE gbọ pe ki Tọpẹ Alabi too pade ọkunrin to n ta fiimu yii, ọkunrin naa ti niyawo kan sile, ṣugbọn tiyẹn ko rọmọ bi.

Lokeṣan kan ni wọn sọ pe Tọpẹ ati ọkunrin yii ti pade, nibẹ ni ere ifẹ ti bẹrẹ laarin Tọpẹ Alabi ati ọkunrin to n ta fiimu yii, to si loyun fun un.

Oyun to ni fun ọkunrin yii ni wọn sọ pe o da wahala nla silẹ laarin Ọlaoye ati obinrin to kọkọ fẹ tiyẹn fi ko kuro nile, ti Tọpẹ si ko wọle Ọlaoye lagbegbe Ṣomolu, l’Ekoo.

Fun ọdun meji ni wọn sọ pe wọn jọ gbe gẹgẹ bii lọkọ-laya, ile ọkunrin yii naa si lo bimọ ọhun si, tiyẹn fi sọ ọmọ naa ni Mary Ayọmikun Oyegoke ni nnkan bii ọdun mejilelogun sẹyin.

Ṣiwaju si i, ẹni to ba wa sọrọ yii sọ pe ko ju ọdun meji ti wọn fi jọ gbe pọ ti wahala fi bẹ silẹ laarin wọn, ti kaluku si ba tiẹ lọ.

Nigba ta a bi i lori ohun to mọ nipa itọju ọmọ ti wọn bi funra wọn yii, ẹni to sọrọ yii sọ pe oun ko le sọ pato boya Ọgbẹni Ọlaoye n ṣẹtọ lori ọmọ ẹ, ṣugbọn ohun kan ti oun kan gbọ ni gbogbo igba ti ọrọ ọhun ṣẹṣẹ ṣẹlẹ ni pe niṣe ni Tọpẹ gbe ọmọ naa sa fun Ọlaoye, nitori ija to bẹ silẹ laarin wọn, eyi to mu obinrin olorin ẹmi ọhun ko jade.

ALAROYE gbiyanju lati pe Tọpẹ Alabi lati fidi awọn ohun ti a gbọ yii mulẹ, ṣugbọn nọmba re ko lọ titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

Eyi lo mu wa pe Ọgbẹni Sọji Alabi to jẹ ọkọ Tọpẹ, ti ọmọ naa n jẹ orukọ ẹ bayii. Alaye to si ṣe ni pe gbogbo ohun ti ọmọ naa ti ba iwe iroyin oloyinbo kan sọ, bẹẹ lọrọ ṣe ri, ko ni i wu oun lati fi ohunkohun kun un mọ.

ALAROYE kan si Ọgbẹni Oyegoke lati gbọ tẹnu rẹ, ṣugbọn titi ta a fi kọ iroyin yii tan, nọmba ọkunrin yii ti a n pe ko lọ rara. Bẹẹ ni ko ti i da atẹjiṣẹ ta a fi ranṣẹ si i pada.

2 thoughts on “Awọn to mọ bọrọ ọmọ Tọpẹ Alabi ṣe jẹ ti sọrọ o, wọn ni Ọlaoye gan-an lo lọmọ, ki i ṣe Sọji Alabi

Leave a Reply