Awọn to n ba Gomina Makinde ṣiṣẹ ni baba isalẹ fawọn tọọgi n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn to n ba Gomina Makinde ṣiṣẹ ni baba isalẹ fawọn tọọgi n’IbadanAṣiri idi ti awọn ọmọ iṣọta ṣe gbajoba igboro Ibadan, ti wọn n pawọn èèyàn, tí wọn n hu onírúurú iwa ọdaran, ti wọn sì n mu gbogbo ẹ jẹ ti tu.

Àwọn aláṣẹ ikọ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ lo tu aṣiri naa, wọn ni awọn abẹṣinkawọ gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinia Ṣeyi Makinde, ni baba isalẹ awọn tọọgi wọnyi.

Ajagunfẹyinti Ọlayinka Ọlayanju ti i ṣe alakooso ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ sọ pe awọn to di ipo mu ninu iṣejọba Gomina Makinde lo maa n saaba waa bẹbẹ fun itusilẹ awọn kọlọransi ẹda ti awọn ba mú sọ sí akata awọn fun iwa ọdaran kan tabi omi-in.

“Bẹẹ náà la mu awọn kan fun iwa ọdaran nijọba ibile Ila-Oorun Ariwa Ibadan ni nnkan bíi ọjọ mẹta sẹyin, ti ọkan ninu awọn oludamọran fún gomina (Makinde) waa bẹbẹ pé ká fi wọn silẹ.” Bẹẹ loludari ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ yìí sọ.

O fidi ẹ mulẹ siwaju pe, “mi o ni i darukọ onitọhun ṣugbọn agbegbe NTA n’Ibadan lo ti waa ba mi to bẹrẹ si bẹbẹ pe ka ma ṣe jẹ kí awọn afurasi ọdaran yẹn jiya ẹsẹ wọn. Ṣugbọn mo sọ fún ùn pe ko sí nnkan ti mo le ṣe si i nitori a ti fa wọn lè awọn ọlọpaa lọwọ.”

O waa rọ àwọn olóṣèlú láti máa ba awọn ọmọ ẹyin wọn sọrọ lati máa yago fún iwa jagidijagan to le da alaafia ilu ru.

Ta o ba gbagbe, ọpọ igba lawọn ọmọ iṣọta ti fitina ẹmi awọn eeyan ninu eyi ti wọn ti pa awọn mi-in laiṣẹ lairo láwọn àdúgbo bíi Elekurọ, Ijokodo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lọjọ meji sẹyin lọga agba fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwackukwu Enwonwu, ti fi aidunnu ẹ han si bi iwa ọdaran ṣe pọ lọwọ awọn ọdọ kan ni ipinlẹ naa ati bó ṣe jẹ pe awọn ohun ija alagbara buruku lo n bẹ lọwọ wọn.

Eyi lo mu ki Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji atawọn mọgaji ilu naa ṣepade pẹlu awọn ọdọ ilẹ Ibadan, to si kilọ fun wọn lati sa gbogbo agbara wọn lati dena iwa idaluru lagbegbe kaluku wọn.

 

 

Leave a Reply