Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹrin yii, ileeṣẹ Sifu Difẹnsi ipinlẹ Ogun kede fun awọn akọroyin, pe ko din ni lita epo bẹntiroolu marundinlaaadọta(45litres) tawọn kan ji fa sinu tanka epo lawọn ri loru ọjọ naa, lagbegbe Ifote, nitosi Ipara, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun.
Kọmandanti Hammed Abọdunrin, olori awọn Sifu nipinlẹ Ogun, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mejila oru ọjọ naa ni olobo ta awọn, pe awọn kan gbe tanka wa, wọn si ti bẹ ọpa epo kan, wọn ti n fa epo lati inu rẹ sinu tanka naa.
O ni bawọn ṣe debẹ lawọn to n ṣiṣẹ ibi naa sa lọ, ti wọn yọnda tanka epo ti wọn ti fa naa, epo to si wa ninu ẹ jẹ lita ẹgbẹrun marundinlaaadọta. Abọdunrin fi kun un pe jiji epo wa ko ṣẹṣẹ maa ṣẹlẹ lagbegbe naa, o ni inu igbo ni awọn to n waa ṣiṣẹ ibi yii ti maa n wa, ti wọn yoo fi oru boju waa ji epo ijọba fa lọ.
Ni ti eyi to ṣelẹ yii, ọga Sifu naa ni gbogbo awọn nnkan tawọn ri nibẹ lawọn ti ko pata, o ni ajọ naa yoo ṣewadii lati mọ awọn to ṣiṣẹ naa, wọn yoo si pe wọn lẹjọ ki wọn le jiya to tọ si wọn.
Ọga Sifu Difensi yii sọ pe ẹsekẹse ni oun ti pe awọn NNPC, pe ki wọn waa gbe epo naa lọ.
O waa kilọ fawọn eeyan agbegbe naa atawọn ara abule kaakiri ibẹ, pe ki wọn ma lẹdi apo pọ pẹlu awọn to waa n ji epo wa yii, kaka bẹẹ, niṣe ni ki wọn sowọ pọ pẹlu ajọ Sifu Difẹnsi ti yoo ran wọn lọwọ lati bọ ninu iṣoro awọn ti wọn n ja wọn lole, ti wọn n bẹ ọpa epo kiri.