Awọn to n gba Buhari nimọran lo n ṣi i lọna- Lawan  

Faith Adebọla

Olori awọn aṣofin ilẹ wa, Sẹnetọ Ahmed Lawan, ti koro oju si bawọn eeyan to yi ileeṣẹ Aarẹ po atawọn oludamọran fun Aarẹ lẹka iṣẹ ọba ṣe n ṣakoba fun Aarẹ Mohammadu Buhari, o ni awọn ni wọn n gba baba naa nimọran  ti ko daa lọpọ igba.

Nibi apero ita gbangba kan tile-igbimọ aṣofin agba ṣe niluu Abuja lati jiroro lori awọn abadofin to rọ mọ eto ilera, ni Lawan ti sọrọ yii. O ni bii igba tawọn minisita ati awọn oludamọran Aarẹ n mọ-ọn-mọ fawọ aago itẹsiwaju sẹyin ni, ti wọn ba kọ lati yọju nigba tawọn aṣofin ba n ṣapero lori abadofin, sibẹ ti wọn tun gba Aarẹ lamọran pe ko ma buwọ lu awọn abadofin ọhun lẹyin tawọn ti ṣiṣẹ lori ẹ tan.

Sẹnatọ yii kọminu si bawọn minisita mejeeji feto ilera, Dokita Osagie Ehanire ati Dokita Ọlọrunnibẹ Mamora ko ṣe wa sibi apero ọhun, bẹẹ ọrọ to kan ẹka ileeṣẹ ti wọn n dari gbọngbọn lo lawọn n ṣe apero le lori, tawọn si diidi fiwe pe wọn bo ṣe yẹ.

Lawan ni: “Nigba mi-in, ileegbimọ aṣofin maa ṣiṣẹ lori abadofin, yoo si fi abadofin ọhun ṣọwọ si Aarẹ lati fọwọ si i ko le dofin, ẹnikan aa kan yọju lati gba Aarẹ lamọran buruku pe ko ma buwọ lu abadofin ọhun, paapaa awọn minisita atawọn oludamọran ileeṣẹ Aarẹ lo maa n ṣe kinni ọhun.

Ta a ba si pepade apero lori awọn abadofin, a maa reti pe kawọn eeyan yii yọju ki wọn waa sọ erongba ati aba wọn lori abadofin ọhun, wọn o ni i wa, boya wọn o mọ pe niṣe ni wọn n fawọ itẹsiwaju orileede sẹyin ni.”

Olori awọn aṣofin naa ni niṣe lo yẹ kawọn eeyan yii bọ si gbangba nigba tawọn ba n jiroro abadofin to kan wọn, karaye le mọ ero ọkan wọn, kawọn naa si tẹti si ero araalu, dipo ti wọn aa maa fun Aarẹ lamọran lori abadofin to yẹ ko buwọ lu ateyi ti ko gbọdọ buwọ lu.

Leave a Reply