Awọn to n gbowo ni banki ni Smart atọrẹ ẹ n digun ja lole

Faith Adebọla

Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn adigunjale meji kan, Smart ati Oluchukwu, wọn jẹwọ pe banki lawọn ti n jale ni tawọn, awọn Kọsitọma ti wọn ba waa gbowo ni banki ni awọn gende meji yii maa n dena de

Ayika banki kan, nibi tawọn mejeeji fara pamọ si niluu Agbor, nijọba ibilẹ Ika, nipinlẹ Delta, lọwọ ẹṣọ alaabo Agbor Gha-Ihun Security, AGS, ti tẹ wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹwaa yii.

Ọga agba AGS, Kọmureedi Monday Kiyem, sọ ninu atẹjade kan to fi lede pe oun ati awọn ẹmẹwa oun n lọ sibi ipade pataki kan ti wọn fẹẹ ṣe pẹlu awọn lọgaa-lọgaa banki to wa lagbegbe Orogodo, ni wọn ba kẹẹfin awọn afurasi yii, wọn lugọ de awọn kọsitọma ti wọn n jade ni banki, atawọn to n wọle, lati ja wọn lole. O ni bawọn ṣe fẹẹ mu wọn lawọn afurasi naa ki ere mọlẹ, ki wọn too le wọn ba. Igba tọwọ tẹ wọn ni wọn ri i pe nnkan bii oṣu marun-un sẹyin lawọn doola ẹmi eyi to pera ẹ ni Smart nibi tawọn ọdọ ti n lu u bii kiku bii yiye, nigba to lọọ digun jale lagbegbe ọja Baleke, diẹ lo ku ki si wọn dana sun un lọjọ naa. Lẹyin eyi lo sa lọ latimọle ti wọn fi i si, ṣugbọn o ya awọn lẹnu pe ọkunrin yii ko ronu piwada, niṣe lọmọ elepo rẹ tun igo rẹ fọ, idi ole jija ọhun lo pada si.

Wọn lafurasi yii ti jẹwọ o, o ni baale ile loun, ọmọ meji loun si ti bi, ipinlẹ Imo niyawo atọmọ oun wa. O ni loootọ ni wọn ti mu oun ri, igba toun raaye sa lọ lahaamọ ti wọn fi oun si lọjọsi loun pade ekeji oun, Oluchukwu, ero awọn si papọ, lawọn fi bẹrẹ si i jale, ko si ti i ju ọsẹ kan tawọn bẹrẹ lọ.

Monday ni ibọn ati awọn nnkan ija mi-in ni wọn ba lọwọ awọn afurasi yii, awọn si ti ṣeto lati fa wọn le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ, ki wọn le wọ wọn rele-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply