Awọn to n pariwo Orilẹ-ede Oduduwa kiri yii, oponu ni wọn o – Arẹgbẹṣọla

Faith Adebọla 

Minisita fọrọ abẹle nilẹ wa, to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ti sọ pe ọrọ oponu loun ka bawọn kan ṣe n pariwo kiri pe ki Yoruba ya kuro lara Naijiria lawọn fẹ, o lọrọ naa o jọ tẹni to ni laakaye rara, tori wọn ko ro ti ogun abẹle to le tidi ẹ yọ mọ ọn.

Nilu Ileṣa, ipinlẹ Ọṣun lọkunrin naa ti sọko ọrọ ọhun nibi ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹrinlelọgọta rẹ to waye lọjọ Abamẹta, Satide yii.

O ni awọn to n rin kiri pe afi ki Orilẹ-ede Oduduwa da duro yii ko ronu ohun o ṣee ṣe ko ṣẹlẹ si awọn obinrin, awọn ọmọde atawọn arugbo tabi awọn akanda ẹda (alaabọ ara) ti ọrọ naa ba lọọ yi biri, to dogun.

Arẹgbẹsọla ko sọna abayọ mi-in fun wa lorilẹ-ede yii ju pe ka wa niṣọkan papọ lọ, ka ṣe araawa loṣuṣu ọwọ, tori laijẹ bẹẹ, afaimọ ni awọn oyinbo amunisin ko tun ni i ko ilẹ adulawọ (Africa) lẹru lẹẹkan si i.

Nigba to n sọrọ ọhun ni gbọngan igbalejo nla ti otẹẹli Zenabab, niluu Ileṣa, Rauf ni, “Naijiria yii lo maa gba awọn orileede yooku nilẹ Afrika silẹ lọwọ awọn aninilara, tori naa, ẹ ma tẹle awọn ti wọn fẹ ka pin yẹlẹyẹlẹ rara.

“Ohunkohun to ba le da iṣoro silẹ fun Naijiria, a o gbọdọ gba a laaye, tori nnkan naa tun maa da wa pada si ibi ta a ti kuro ni aadọta ọdun sẹyin ni”. Bẹẹ l’Arẹgbẹṣọla ọlọjọọbi sọ.

Leave a Reply