Awọn to n ta ko awọn gomina Guusu lori ofin fifi maaluu jẹko n fina ṣere – Fani-Kayọde

“Ẹ sọ fọkunrin yii ko yee fi ina ṣere. Bii ẹni n fi ina ṣere ni fun gbogbo awọn to n ta ko ipinnu tawọn gomina ipinlẹ mẹtadinlogun iha Guusu ilẹ wa ṣe pe awọn o fẹ fifi maaluu jẹko ni gbangba mọ. Alaafia la fẹ, a si nawọ alaafia si wọn, ṣugbọn bi ẹnikẹni ba gbiyanju lati halẹ, ṣatako, tabi mu wa lẹru lori ọrọ yii, onitọhun maa jẹ iyan rẹ niṣu ni, tori a o ni i gba ijẹgaba kankan mọ.”

Minisita lori igboke-gbodo ọkọ ofurufu nilẹ wa tẹlẹ, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, lo sọrọ yii lati fesi si bawọn kan ṣe n yọ ṣuti si awọn ipinnu tawọn gomina ipinlẹ Guusu ilẹ wa ṣe ninu apero wọn lọjọ Iṣẹgun to kọja yii.

Ọkan ninu ipinnu naa to da awuyewuye silẹ titi di ba a ṣe n sọ yii ni ti ifofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba, wọn lawọn o fẹẹ ri iru nnkan bẹẹ lagbegbe awọn mọ.

Ọkan lara awọn to koro oju si ipinnu naa ni Ọga agba ileeṣẹ abanigbofo ilera ilẹ wa (NHIS) nigba kan, Ọjọgbọn Usman Yusuf, o sọ pe bawọn gomina naa ṣe ṣe iru ipinnu pataki bẹẹ lai kọkọ fọrọ lọ awọn Fulani darandaran tọrọ kan ko bojumu. O lawọn gomina bii mẹtala o kan le lọọ jokoo sotẹẹli kan, ki wọn lawọn n sọrọ, awọn n ṣepinnu, lori ẹya mi-in lai ba awọn ẹya naa sọrọ, o ni ipinnu buruku ni.

Ọrọ yii ni Fani-Kayọde n fesi si to fi gba ori atẹ ayelujara tuita (twitter) rẹ lọ, o ni “Ijọra-ẹni-loju ati aya to ko ọkunrin yii ya mi lẹnu o. Kawọn gomina ilẹ Guusu kọkọ kan sawọn Fulani ki wọn too ṣepinnu, tori kinni, ki lo fẹẹ ni ki wọn kọkọ ba awọn olori Fulani sọrọ lori ipinnu to kan iṣakoso lagbegbe kaluku wọn si? Ṣe ẹru lawọn eeyan Guusu ni? Ki lo ni lọkan to fi n sọ pe kawọn gomina naa ṣọra wọn?

Oloye Fani-Kayọde ni oun fara mọ ipinnu tawọn gomina naa ṣe, o ni igbesẹ to daa gidi ni. O lawọn to fẹẹ ri pipọn oju awọn eeyan Guusu nikan lo le ta ko iru ipinnu bẹẹ.

Leave a Reply