Awọn to ni ibaṣepọ pẹlu Logun ti wa ni iyasọtọ – Ijọba Kwara

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe gbogbo awọn to ni ibaṣepọ pẹlu Aminu Logun, olori oṣiṣẹ lọfiisi gomina to doloogbe, lati bii ọjọ mẹrinla sẹyin ti wa ni iyasọtọ bayii, wọn si ti ṣayẹwo fun arun Koronafairọọsi.

Logun lo jade laye lanaa, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lẹyin ti ayẹwo to ṣe fi han pe o ni arun Koronafairọọsi.

Ṣaaju ni kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Kwara, Dokita Raji Razaq, ti kede pe oni, Ọjọru, Wẹsidee, ni wọn yoo sin olori oṣiṣẹ ọhun sile rẹ to wa ni GRA, niluu Ilọrin.

Razaq ni ko ni i si aaye fun ero rẹpẹtẹ nibi eto isinku naa nilana ajọ to n gbogun ti arun nilẹ yii (NCDC), ikọ to n mojuto isinku awọn ti arun Korona ba pa ni yoo si sin oku ọhun.

Awọn to lanfaani lati wa nibẹ ni Imaamu agba ilu Ilọrin, diẹ lara awọn ẹbi oloogbe naa, awọn aafaa perete ti Ọba Ilọrin ba yan, ati diẹ lara awọn alaṣẹ ijọba.

Laaarọ oni ni kọmiṣanna feto iroyin, Henrietta Afọlabi-Ọshatimẹhin, kede pe awọn tọrọ kan ti lọ iyasọtọ. Awọn eeyan naa ni awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ, awọn oṣiṣẹ Oloogbe Logun atawọn eleto ilera kan.

Afọlabi-Ọshatimẹhin ni ijọba Kwara tun ti da gbogbo ipade tabi apero duro  lati gbe iru igbesẹ ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, eyi ti yoo di kawọn eeyan maa sunmọ ara wọn ku.

O waa sọ ọ di mimọ pe ọjọ kẹfa, oṣu kẹrin, ọdun yii, ni gomina ni ibaṣepọ pẹlu oloogbe Logun gbẹyin, iyẹn lasiko tijọba pin owo fun awọn arugbo.

Leave a Reply