Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Amidu Salami, ti ni ijiya to tọ n bẹ fun gbogbo awọn ti iwadii ba fidi rẹ mulẹ pe wọn lọwọ ninu iku Onifọn tilu Ifọn, Ọba Israel Adeusi.
Ọga ọlọpaa ọhun ṣeleri yii lasiko to ṣabẹwo ibanikẹdun si awọn ẹbi ọba naa niluu Ifọn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.
O ni lati igba tiṣẹlẹ naa ti waye lawọn ti n sa gbogbo ipa to wa ni ikawọ awọn lori bi wọn yoo ṣe ṣawari awọn oniṣẹẹbi ọhun lọnakọna.
O rọ awọn oloye, awọn araalu Ifọn, ati gbogbo olugbe ipinlẹ Ondo, ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu akitiyan awọn agbofinro lori gbigbogun ti ijinigbe, idigunjale ati awọn iwa ọdaran mi-in to n waye.
Ọgbẹni Ṣalami tun bu ẹnu atẹ lu bawọn ọlọpaa kan ṣe kọ lati siṣẹ wọn bii iṣẹ latari rogbodiyan to suyọ ninu iwọde SARS to waye ninu oṣu kẹwaa, ọdun ta a wa yii, eyi to fun awọn ọdaran kan laaye ki wọn maa ṣe ohun to wu wọn.
O ni asiko ti to fawọn oga ọlọpaa ẹkun ati tesan kọọkan lati gbaradi lati gbogun ti ọkan-o-jọkan ipenija eto aabo to n koju awọn eeyan ipinlẹ Ondo lasiko yii.
Awọn ọlọpaa ọhun lo ni wọn gbọdọ ri i daju pe eto aabo ẹmi ati dukia awọn araalu fẹsẹ mulẹ lagbegbe wọn lasiko opin ọdun ta a wa yii.