Awọn tọọgi da eto idibo ru niwaju aafin Elegushi

Faith Adebọla

 Yatọ si bawọn araalu ṣe n jẹrii pe eto idibo gbogbogboo to n lọ lọwọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji yii, waye nirọwọ-irọsẹ lọpọ ibudo idibo, ọrọ naa ko ri bẹẹ nibudo idibo kan to wa niwaju aafin Ọba Elegushi, ni Ikate, nijọba ibilẹ Eti-Ọsa, lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko, wọn ni niṣe lawọn janduku ya bo wọn lasiko ti eto idibo n lọ lọwọ, wọn ji apoti ibo gbe, wọn si le gbogbo oludibo atawọn oṣiṣẹ INEC danu, wọn tun ba foonu awọn ti wọn n ya wọn jẹ.

Olugbe agbegbe ọhun tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ sọ pe “Iwaju aafin kabiyesi gan-an ni wahala ti ṣẹlẹ. Ojiji lawọn janduku ya de, wọn bẹrẹ si i ji apoti ibo gbe, wọn n ba nnkan eelo idibo jẹ.

Ọkunrin kan toun n jẹ Samuel Otigba sọ loju opo tuita rẹ pe “inu aafin lemi ti dibo, amọ wọn ti da ibudo idibo to wa niwaju aafin Elegushi ru, wọn ji apoti ibo gbe, wọn le oṣiṣẹ ajọ INEC to fẹẹ di wọn lọwọ danu.”

Mo ri i ti wọn kọ lu Ọgbẹni Edith Effiong nigba ti wọn ri i pe o n fi foonu kamẹra akọlu yẹn, wọn le e mu bo ṣe ku diẹ ko sa wọnu aafin, wọn fipa gba foonu ẹ lọwọ ẹ, wọn si pa gbogbo nnkan to ya naa rẹ. Eyi to ya mi lẹnu ju ni pe niṣe lawọn ọlọpaa kan duro ta-n-di sibẹ ti wọn n woran wọn, wọn o tiẹ mira rara. Gbogbo agbegbe yii lo n gbona janjan bayii.”

Amọ, Alaroye gbọ pe awọn ṣọja ti lọ sibi iṣẹlẹ naa, wọn si ti da alaafia pada sibudo idibo ọhun, bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn oludibo ni ko pada waa dibo mọ.

Leave a Reply