Awọn tọọgi dana sun Sekiteeria Ajerọmi, wọn tu kọ lu teṣan Cele, lawọn ọlọpaa ba fere ge e

 Pẹlu ibọn atawọn ohun ija oloro mi-in ni awọn ọmọ ganfe kan ya wọn ijọba ibilẹ Ajerọmi, ti wọn si dana sun awọn ofiisi kan ninu sekiteriati naa, bẹẹ ni wọn wọ awọn ọfiisi kan lọ, ti wọn si n ji awọn eru oriṣiiriṣii to wa nibẹ ko.

ALAROYE gbọ pe bi wọn ṣe n ji ẹru ko lawọn ọfiisi kan ni wọn n dana sun awọn mọto to wa ninu ọgba ijọba ibilẹ naa.

Bakan naa ni wọn ni awọn ọmọ isọta yii ti ya wọ agọ ọlọpaa to wa ni Sele, ni Isọlọ. Bẹẹ ni wọn kọju ija si awọn ọlọpaa, ti wọn si bẹrẹ si ko awọn nnkan ti wọn ri lọ lagọọ ọlọpaa naa. Niṣe ni aọn ọlọpaa fere ge e, ti onikaluku sa asala fun ẹmi rẹ.

Leave a Reply