Awọn tọọgi kọ lu kọmisanna, wọn tun ṣe awọn mi-in leṣe nibi iforukọsilẹ ẹgbẹ APC n’Iju

Oluṣẹyẹ Iyiade

 

Ọpọlọpọ eeyan lo fara pa ninu rogbodiyan kan to bẹ silẹ nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti n ṣepade niluu Iju, nijọba ibilẹ Iju/Ita-Ogbolu, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to pari yii.

Alaga ẹgbẹ APC nijọba ibilẹ ọhun, Ọgbẹni Joshua Eleti, ni wọn lo ko awọn agbaagba kan jọ sinu gbọngan nla kan to wa niluu Iju lọjọ naa lati jiroro lori ọrọ iforukọsilẹ ọmọ ẹgbẹ, eyi ti wọn fẹẹ bẹrẹ jake-jado orilẹ-ede yii laipẹ rara.

Ko ju bii isẹju marun-un ti kọmiṣanna feto iṣẹ ode, Ọnarebu Saka Ogunlẹyẹ, de sibi ipade naa nigba tawọn tọọgi kan ya bo wọn pẹlu awọn nnkan ija loriṣiiriṣii, ti wọn si n po ẹkọ iya fun gbogbo wọn.

Ori kọmisanna yii ni wọn ti kọkọ bẹrẹ, wọn si lu u ṣe leṣe ki wọn too fabọ sori awọn yooku.

Ẹnikan to wa nibi iṣẹlẹ naa to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ni airotẹlẹ lawọn janduku ọhun waa ba awọn ki ipade too bẹrẹ rara.

O ni Ọlọrun lo ko Ọnarebu Ogunlẹyẹ yọ lọwọ awọn tọọgi naa pẹlu bi wọn ṣe lu u lalubolẹ ki awọn ọmọ ẹyin rẹ kan too fipa gba a silẹ lọwọ wọn.

Ọkunrin to b’ALAROYE sọrọ yii ni o da oun loju pe minisita keji fun ileeṣẹ Niger/Delta, Tayọ Alaṣọadura, lo wa nidii akọlu naa, nitori pe awọn alatilẹyin rẹ lawọn ri ti wọn waa da ipade ọhun ru.

Ninu ọrọ Eleti to jẹ alaga nijọba ibilẹ Iju/Ita-Ogbolu, o ni gbogbo awọn aṣaaju ẹgbẹ loun fiwe pe ki wọn jọ waa jiroro lori iforukọsilẹ naa.

O ni lẹyin ti gbogbo awọn ti jokoo tan, ti awọn si n reti ki ipade bẹrẹ lawọn ọdọ ọhun ya de, ti wọn si fipa le awọn jade ninu gbọngan ti awọn pe jọ si.

Alaga ọhun rọ Gomina Rotimi Akeredolu lati tete wa nnkan ṣe sọrọ Oloye Alaṣọadura to fẹẹ maa da ẹgbẹ APC ru nijọba ibilẹ Iju/Ita-Ogbolu.

Akọwe iroyin fun minisita ọhun, Ọgbẹni Dayọ Joe, ni irọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni wọn pa mọ ọga oun.

O ni Ṣẹnetọ Alaṣọadura ki i ṣe ọmọde ninu oṣelu siṣe, ko si ni i fara rẹ wọle debi ti yoo ṣẹṣẹ maa fi tọọgi le Ogunlẹyẹ kiri.

Dayọ ni iwọnba awọn alatilẹyin nìkan ni wọn pe sibi ipade, o ni o ṣee ṣe ko jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn kọ lati pe sibi ipade naa ni wọn waa binu tu wọn ka.

Leave a Reply