Awọn tọọgi kọju ija sira wọn l’Ejigbo, ni wọn ba yinbọn pa Abeeb

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọdekunrin kan, Abeeb Abifarin, lo ti jẹ Ọlọrun nipe laago mẹjọ ku diẹ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọse yii, lasiko ti awọn tọọgi kọju ija sira wọn niluu Ejigbo, nipinlẹ Ọṣun.

Awọn tọọgi naa, ti awọn kan n jẹ Lion Base Club lagboole Olukọla, ti awọn abala keji si n jẹ Isalẹ Agooji Club, la gbọ pe wọn bẹrẹ wahala ọhun lagbegbe Orieeru, nirọlẹ ọjọ Aje, ko too di pe wahala naa tan kaakiri inu ilu.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (#150,000) ti ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ kan to ri irinṣẹ wọn (mast), mọbẹ fun wọn lo da wahala silẹ.

Lẹyin ti ibọn ba Abeeb ni wahala naa burẹkẹ si i, gbogbo awọn eeyan agbegbe  Sagan, Orieru, Port Junction ati Roundabout, ni wọn n sa kijokijo kaakiri.

Gbogbo awọn oṣiṣẹ to yẹ ki wọn lọ si sẹkiteriati ijọba ibilẹ Ejigbo laaarọ ọjọ naa ni wọn sa pada latari bi ibọn ṣe n dun lakọlakọ kaakiri.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iku Abeeb mulẹ, o ni Mutiu to jẹ ẹgbọn oloogbe lo lọọ fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti, awọn ọlọpaa si ti gbe oku rẹ lọ fun ayẹwo nileewosan.

Ọpalọla ṣalaye pe alaafia ti pada sagbegbe naa nitori awọn ọlọpaa ko dawọ iṣẹ duro nibẹ lataarọ.

Leave a Reply