Awọn tọọgi kọlu ile Arẹgbẹṣọla l’Oṣogbo, wọn ni ṣe ni wọn fẹẹ dana sun un

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ile nla ti gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, maa n lo fun ipolongo ibo ti wọn pe ni Ọranmiyan House, niluu Oṣogbo, ni awọn tọọgi kọlu tibọn-tibọn nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti awọn igun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun ti wọn jẹ ọmọlẹyin Arẹgbẹṣọla, iyẹn TOP, ṣe ipade ọlọsọọsẹ wọn tan nibẹ.

Bi iro ibọn ṣe bẹrẹ si i dun niwaju ile naa to wa loju-ọna Oṣogbo si Gbọngan, niluu Oṣogbo, lawọn ti wọn wa lagbegbe naa n sa kaakiri fun ẹmi wọn.

Alaroye gbọ pe bi awọn tọọgi naa ṣe n yinbọn si gilaasi ile nla naa ni wọn n yinbọn si ẹrọ amunawa kan to wa ninu ọgba nibẹ.

Bi wọn ṣe yinbọn si tẹnti to wa nibẹ ni ina bẹrẹ, awọn ti wọn n taja lagbegbe yẹn ni wọn si pana naa lẹyin ti awọn tọọgi naa lọ tan.

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju ẹ, Ṣeun Abọsẹde, ti gbogbo eeyan mọ si Safety, ṣalaye pe mọto meji;  Sienna alawọ pupa kan ati bọọsi Toyota Hiace kan ni awọn tọọgi naa gbe wa.

O ni ọna Ogo-Oluwa lawọn eeyan naa gba wa, ibọn Pump Action si ni wọn gbe lọwọ ti wọn n yin. O ni ọta ibọn ti awọn ṣa nilẹ to ọgbọn.

O fi kun un pe bii iṣẹju mẹẹẹdogun ni wọn fi ṣiṣẹ naa, bi wọn si ṣe tẹ ifẹ inu ara wọn tan ni wọn lọ.

Leave a Reply