Awọn tọọgi pa oṣiṣẹ Operation Burst nitosi Ogbomọṣọ 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Idarudapọ ṣẹlẹ niluu Iluju, nitosi Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, pẹlu bi awọn ọdọ agbegbe naa ṣe lu oṣiṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ọyọ ta a mọ si Operation Burst kan pa, ti wọn si tun dana sun mọto awọn agbofinro naa lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Iṣẹlẹ buruku yii lo ko awọn araadugbo naa sinu ifoya, nitori ikọlu ojiji to ṣee ṣe kawọn ṣọja atawọn eleto aabo yooku ṣe si agbegbe naa nigba ti wọn ba ṣetan lati gbẹsan, paapaa nitori pe ṣọja lọkunrin ti wọn pa nipakupa naa.

Tẹ o ba gbagbe, Operation Burst, eyi ti ijọba ipinlẹ Ọyọ da silẹ lasiko iṣejọba Oloogbe Abiọla Ajimọbi, lo ko ọpọlọpọ oṣiṣẹ agbofinro bii ṣọja, ọlọpaa, sifu difẹnsi ati bẹẹ bẹẹ lọ sinu.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, nibi ere bọọlu alafẹsẹgba ni wahala ọhun ti bẹ silẹ nigba tọkunrin kan ti wọn pe lọmọ iṣọta deede wa mọto rẹ gunlẹ si aarin gbungbun ori papa ti awọn agbabọọlu Iluju ti fẹẹ ba ẹgbẹ agbaboolu kan figagbaga.

Ija nla bẹ silẹ laarin awọn to fẹẹ gba bọọlu atawọn ikọ ti ko fẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa waye. Ija ọhun si gbona to bẹẹ ti ẹru fi bẹrẹ si i ba awọn ara agbegbe naa pe ki ija yii ma lọọ la ọpọ ẹmi lọ tabi ko ma lọọ dija igboro. Eyi lo si mu wọn pe awọn agbofinro ta a mọ si Operation Burst lati waa pana ija naa.

Ibọn lawọn oniyẹn kọkọ yin soke kosa! Kosa! nigba ti wọn ya wọ ori papa isere naa toguntogun. Ẹru ba gbogbo eeyan, to bẹẹ ti ọmọkunrin kan fi daku gbọnrangandan.

Iku lawọn eeyan ro pe ọmọkunrin yii ti ku, wọn o mọ pe ọ daku lasan ni, n lawọn ọmọ aye ba suru bo ṣọja to yinbọn, nigba ti awọn ẹgbẹ ẹ yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti gbẹmi ọkunrin naa pẹlu apola igi ati oniruuru ohun ija oloro ọwọ wọn.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin, Oludari ikọ Operation Burst nipinlẹ Ọyọ, Ajagun-fẹyinti Ọladipọ Ajibọla, sọ pe loootọ ni wọn pa ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ajọ naa nibi laasigbo ọhun, ṣugbọn ẹni naa ki i ṣe ṣọja.

“Niṣe lawọn janduku yẹn lọọ ṣigun ba awọn eeyan wa, wọn pa ọkan ninu wa, wọn si dana sun mọto wa.”

Leave a Reply