Awọn tọọgi ya wọ ọsibitu l’Oṣogbo, wọn gbe oku awọn ti dokita sọ pe korona pa

Florence Babaṣọla

 

 

Ere asapajude lawọn dokita, nọọsi atawọn alaisan ti wọn wa ninu ọgba ileewosan Osun State University Teaching Hospital, Oṣogbo, sa lopin ọsẹ to kọja, nigba ti awọn tọọgi ya wọbẹ, ti wọn si n pariwo pe ẹni ba duro gbe.

Awọn eeyan meji la gbọ pe wọn ku nipasẹ arun Korona to kọ lu wọn, ṣugbọn esi ayẹwo yii ko tẹ awọn mọlẹbi wọn lọrun, wọn si ni dandan ni ki wọn gbe oku wọn silẹ fun awọn.

Gbogbo alaye awọn alaṣẹ ileewosan naa pe wọn ko le deede gbe oku alarun Korona silẹ fawọn mọlẹbi lai tẹlẹ gbogbo ilana ti ajọ NCDC gbe kalẹ ni ko wọnu eti awọn eeyan ọhun.

Bayii ni wọn lọọ ko awọn tọọgi wa, ti wọn si bẹrẹ si i da gbogbo ẹka ti wọn ti n tọju awọn ti wọn ba ni asidẹnti ati itọju pajawiri, Accident and Emergency Unit ru.

Iṣẹlẹ naa la gbọ pe o gba awọn alaṣẹ ileewosan naa atawọn agbofinro ni ọpọlọpọ wakati lati yanju lọjọ naa.

Nigba to n sọrọ lori ẹ, Oludari agba funleewosan naa, Ọjọgbọn Peter Ọlaitan, ṣalaye pe awọn mọlẹbi awọn mejeeji ti wọn doloogbe naa sọ pe esi ayẹwo to jade pe wọn ni Korona naa jinna soootọ.

Ọlaitan ni ṣe ni wọn bẹrẹ si i da wahala silẹ pe awọn fẹẹ gba awọn oku naa fun sinsin, ṣugbọn ileewosan gbagbọ pe wọn gbọdọ tẹle ilana ajọ NCDC ki arun naa ma baa di tọrọ fọn kale.

O ni awọn pada yanju wahala naa, ati pe ko si alaisan kankan to nipalara lasiko yẹn.

Leave a Reply