Awọn TOP fẹsun kan Oyetọla, wọn lo ran tọọgi lati da ipade awọn ru

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ere asapajude lawọn eeyan agbegbe Gbodofọn ati Fakunle, niluu Oṣogbo, sa lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, nigba ti awọn tọọgi ya bo ile Ọranmiyan, nibi ti awọn TOP ti n ṣepade wọn, ti wọn si n yinbọn soke lakọlakọ.

Ọsọọsẹ ni awọn TOP ti wọn jẹ abala kan ninu ẹgbẹ APC Ọṣun ti wọn fara mọ Minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, maa n ṣepade wọn ni ile Ọranmiyan.

Wọn ti bẹrẹ ipade wọn bii iṣe wọn nigba ti awọn tọọgi ọhun de tibọntibọn, bọọsi Sienna alawọ dudu la gbọ pe awọn eeyan naa gbe wa, ti gbogbo nnkan si di bo o lọ o ya lọna.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa, alaga TOP, Lọwọ Adebiyi fẹsun kan Gomina Oyetọla pe oun lo ran awọn tọọgi naa wa.

Adebiyi ke si Aarẹ Muhammadu Buhari ati ọga agba patapata ni ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣewadii ikọlu naa, ki wọn si fi oju awọn ti wọn wa nidii rẹ han araye.

O ni pupọ ninu awọn eeyan oun ni wọn fara pa lasiko ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn, ati pe aisi awọn Sifu Difẹnsi ti wọn maa n pese aabo fun awọn lasiko ipade nibẹ lo fa a ti awọn tọọgi IleriOluwa fi raaye huwa laabi naa.

Ṣugbọn nigba to n fesi si ẹsun naa, Akọwe iroyin fun gomina, Ismail Omipidan, sọ pe ọga oun ki i ṣe oniwahala rara, bẹẹ ni ko si fẹran jagidijagan.

Omipidan ni ki i ṣe igba akọọkọ niyi ti Adebiyi Adelọwọ yoo pa irọ bantabanta bayii mọ Gomina Oyetọla, yoo si wu oun ki Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ṣe gaafara fun un ko ma baa ba aṣọ aala rẹ jẹ.

O ni iwadii oun fidi rẹ mulẹ pe ọkan lara awọn adari TOP, Rasaq Ṣalinṣile, ṣe ipade pẹlu ọkan lara awọn ti wọn lọọ da ipade wọn ru l’Ọjọbọ yii, ṣe lo kan fẹẹ ti ọrọ naa si ọrun gomina.

Omipidan waa ke si awọn agbofinro lati ma ṣe fi ọwọ kekere mu ọrọ Adebiyi rara nitori o da bii ẹni pe o ni nnkan biburu kan lọkan to fẹẹ ṣe.

Leave a Reply