Awọn to n ṣewọde SARS tilẹkun Sẹkiteriati ijọba Eko pa, wọn ni kawọn oṣiṣẹ pada sile

 Kazeem Aderohunmu

Ni Sẹkiteriati ileeṣẹ ijọba Eko, iyẹn ni Alausa, n’Ikẹja, lawọn ọdọ to n ṣewọde ta ko SARS atawọn iwa mi-in duro wamuwamu si lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti wọn si n le awọn oṣiṣe pada sile wọn.

ALAROYE gbọ pe gbogbo ilẹkun to wọ ọfiisi ijọba pata ni wọn ti pa, bi wọn ṣe n le awọn eeyan, bẹẹ ni mọto paapaa ko le wọle pẹlu.

Ojuna kan ti wọn pe ni Governor’s road, ni Alausa, wa lara ibi ti awọn ọdọ yii maa n wa latijọ ti iwọde ọhun ti bẹre, ti wọn si fi iwaju ile-igbimọ aṣofin Eko ṣe ibi ipagọ ti wọn ti n fẹhonu han. Bi wọn ṣe n sun sibẹ, bẹẹ lawọn mi-in ko ni ibi meji ti wọn n lọ ju gbagede naa lọ lojoojumọ.

Ṣaaju asiko yii lawọn ọdọ ti wa ni Alausa, ti wọn n ṣe tiwọn, tawọn oṣiṣe ijọba paapaa n ba iṣẹ wọn lọ, tẹnikẹni ko si dira wọn lọwọ. Ṣugbọn nibi ti ọrọ ọhun gba laaarọ yii, awọn kan lo jọ pe, wahala rẹpẹtẹ ti apa le ma ka, lo n wọle bọ wẹrẹwẹrẹ yii.

Leave a Reply