Aye le o, Adamu ran awọn agbanipa si ọga ẹ l’Agbado

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ileepo kan ti wọn n pe ni ‘Inspiration’, eyi to wa lagbegbe Matọgun, l’Agbado, ipinlẹ Ogun, ni ọkunrin yii, Adamu  Ibrahim, ti n ṣiṣẹ aṣọgba. Ṣugbọn bo ṣe n ṣiṣẹ nibẹ to naa lo n pete iṣubu fẹni to gba a siṣẹ, niṣe lo ni kawọn ọmọọta lọọ dena de ọga ẹ lọna, owo to to miliọnu mẹta naira lo ni ki wọn gba lọwọ ọkunrin naa bọwọ wọn ba to o, ki wọn si pa a pẹlu.

Ohun ti DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣalaye f’ALAROYE lori iṣẹlẹ yii ni pe awọn ọmọkunrin meji kan, Ajibọla Yusuf ati Bakare Ifakayọde, ni Adamu lọọ bẹ lọwẹ pe ki wọn ba oun da ọga oun lọna to ba n lọ sile ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ.

Adamu ṣalaye fawọn ọkunrin meji yii pe ọkada ni ọga oun to jẹ maneja ile-epo naa maa gbe kọja, o sọ ọna ibi to maa n gba fun wọn, bẹẹ lo sọ iru ọkada ti yoo gbe kọja.

Afikun to ṣe fawọn to bẹ lọwẹ ni pe owo ti yoo wa lara ọga oun naa yoo to miliọnu mẹta naira, o ni bi wọn ba ti rowo ọhun gba lọwọ ẹ tan, niṣe ni ki wọn pa a patapata, ko ma di pe ẹnikẹni yoo maa wadii bowo ṣe sọnu lọwọ ẹ tabi ti aṣiri kankan yoo fi tu.

Ṣugbọn ohun ti Adamu ko mọ ni pe awọn ọmọkunrin meji to bẹ lọwẹ yii ki i ṣe iru iṣẹ bẹẹ, awọn funra wọn ni wọn lọọ ta awọn ọlọpaa lolobo ni teṣan Agbado, ti wọn sọ fun DPO Kẹhinde Kuranga pe loootọ lawọn n ṣe bii ọmọọta laduugbo tawọn eeyan si mọ awọn, ṣugbọn awọn ki i ṣe adigunjale, awọn ko si ki i paayan rara.

Wọn ni awọn ko jẹwọ fun Adamu pe awọn ki i ṣe iru iṣẹ bẹẹ, awọn n tan an pe awọn yoo ba a pa ọga rẹ ni, ṣugbọn awọn ko le ṣe bẹẹ, ohun to jẹ kawọn waa sọ fọlọpaa niyẹn.

Ki wọn le ri afurasi naa mu lọrun ọwọ ni awọn ọlọpaa ṣe sọ fawọn gende meji naa pe ki wọn ma fu u lara, wọn ni ki wọn maa ba a sọrọ, ki wọn si maa ṣe bii pe ọwọ awọn ko ti i ba ẹni to ran wọn si ni.

Nigba ti Adamu ko si mọ pe ijọba ti dẹ okun silẹ foun, niṣe lo n pe Ajibọla ati Bakare lori foonu lọpọ igba, to n sọ bi ọga rẹ yoo ṣe tun rin fun wọn, to si n sọ pe ki wọn ṣaa ba oun mu un balẹ bi wọn ba gba owo ọwọ ẹ tan.

Ohun to n ṣe lọwọ naa ree lọjọ tawọn ọlọpaa bo o lopin ọsẹ yii, ti wọn mu un ṣinkun nibi to ti n pete ibi.

O kọkọ n purọ pe oun ko ṣe oun to jọ bẹẹ, oun ko ran ẹnikẹni niṣẹ, ṣugbọn nigba ti wọn mu awọn gende meji naa jade si i pe ko koju wọn, Adamu jẹwọ pe loootọ, oun bẹ wọn pe ki wọn ba oun pa ọga oun.

O tiẹ tun sọ pe nitori awọn ọkunrin meji naa jọ awọn kan to ti ja ileepo toun n ṣọ naa lole ri nigba kan loun ṣe ro pe wọn yoo le ba oun ṣiṣẹ naa lọtẹ yii, koun naa le ri nnkan pọnla ninu iṣẹ ti wọn ba ṣe.

Amọran ti waa lọ sọdọ awọn agbanisiṣẹ pe ki wọn mọ iru eeyan ti wọn yoo maa gba siṣẹ daadaa ki wọn too fiṣẹ ṣe wọn loore.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun,  CP Edward Ajogun, lo fi amọran naa ranṣẹ sawọn eeyan. Bo ṣe paṣẹ pe ki wọn taari Adamu sẹka ti wọn yoo ti wadii ẹ naa lo ni kawọn agbanisiṣẹ maa foju ṣọri ki wọn too gbaayan sibi iṣẹ wọn.

 

Leave a Reply