Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Latigba ti ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress lorilẹ-ede yii ti mu ogunjọ oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ta a wa yii, gẹgẹ bii ọjọ ti wọn ya sọtọ fun eto idibo abẹle ti wọn ti fẹẹ yan oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ ọhun ninu eto idibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni ara awọn to ra fọọmu lati kopa ko ti balẹ mọ.
Awọn mẹrindinlogun ni wọn gba fọọmu, ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ondo ni mẹẹẹdogun ninu wọn ti wa, nigba ti ẹni kan yooku, iyẹn Abilekọ Funmilayọ Waheed-Adekojọ, wa lati Akoko, ni ẹkun idibo Ariwa.
Nigba to n fi erongba rẹ han fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ti eto idibo abẹle ku ọla, Adekojọ ni ofin atọwọdọwọ lasan ni ọrọ pipin ipo gomina si ẹlẹkun-jẹkun nitori ko fidi mulẹ ninu iwe ofin Naijiria.
Bi ara ko ti rọ okun awọn mẹrindinlogun to n figa gbaga naa ni ara ko fi bẹẹ rọ adiyẹ awọn alatilẹyin wọn pẹlu ọkan-o-jọkan oko ọrọ ti wọn n fi ranṣẹ sira wọn.
Aarin awọn alatilẹyin Gomina Lucky Ayedatiwa, Oluṣọla Oke ati Wale Akintẹrinwa, ni kinni ọhun ti le ju, oriṣiiriṣii ẹsun ni wọn si n fi ojoojumọ ka si ara wọn lẹsẹ.
Ilana ṣíṣe amulo awọn aṣoju, eyi ti wọn n pe ni (direct primary) lẹgbẹ APC ti n lo latigba ti wọn ti n yan oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ wọn latẹyinwa, eyi lo fi jẹ kayeefi fawọn eeyan nigba tawọn aṣaaju ẹgbẹ ọhun l’Abuja yi ohun pada lọtẹ yii, ti wọn ni ilana taara, iyẹn (direct primary) ni awọn fẹẹ lo.
Wọn ni kawọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn ko ti ni kaadi tete lọọ maa forukọ silẹ kiakia, ki wọn si maa sanwo oju ọdun wọn.
Awọn oloṣelu to n dije ni wọn gba iṣẹ ọhun ṣe, bẹrẹ lati ori Gomina Ayedatiwa, Oluṣọla Oke, Wale Akintẹrinwa, Jimoh Ibrahim atawọn mi-in, awọn ni wọn gbe gbogbo owo to yẹ kawọn ọmọ ẹgbẹ san nitori ibo tí wọn n wa lọdọ wọn.
Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Ondo, Dokita Banji Ajaka, ko ni i gbagbe ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ti idibo abẹle ọhun waye, pẹlu b’awọn eeyan tinu n bi kan ṣe lu u lalubami lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o mọ-ọn-mọ fi awọn esi ibo ti wọn di ni Wọọdu kẹta, niluu Ugbo, nijọba ibilẹ Ilajẹ, pamọ fawọn eeyan.
ALAROYE gbọ pe oṣiṣẹ ajọ eleto idibo to n mojuto ibo ti wọn di ni wọọdu ọhun ti i ṣe ilu abinibi Ajaka, ni wọn lo tawọ si ọkunrin naa nigba ti wọn beere ibi ti iwe ibo ti wọn di wa lọwọ rẹ.
Awọn eeyan ko jẹ ko raaye ṣalaye ẹnu rẹ ti wọn fi dawọ jọ bo o, ti wọn si lu u bii ẹni lu ẹgusi baara.
Ohun to fiya jẹ kọmisanna yii ni pe awọn alatilẹyin Oluṣọla Oke lo pọ ju lagbegbe ta a n wi yii, wọn ko si fẹẹ gbọ ọrọ Ayedatiwa seti rara.
Ajaka funra rẹ fidi eyi mulẹ ninu ọrọ to ba oniroyin wa sọ pe awọn tinu n bi ọhun ko fun oun lanfaani lati sọ bi ọrọ ṣe jẹ ti wọn fi lu oun ni ilukilu.
Bakan naa ni wọn fẹsun kan Kọmisanna tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bura wọle fun nipinlẹ Ondo, Saka Yusuf Ogunlẹyẹ, pe oun atawọn tọọgi rẹ lu akọroyin NAN kan ti wọn porukọ rẹ ni Tayọ Ikujuni, lasiko to n ṣiṣẹ rẹ ni Wọọdu kẹsan-an, niluu Ọba-Ile, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ. Lẹyin ti wọn na akọroyin ọhun tan ni wọn tun gba tabulẹẹti Samsung to fi n ṣiṣẹ, ti wọn si binu fọ ọ mọlẹ.
Lati bii aago mẹjọ alẹ lawọn akọroyin ti rọ lọ si gbọngan Doomu, to wa niluu Akurẹ, ti wọn si n retí ki Ododo atawọn ẹmẹwa rẹ de ki eto bẹrẹ ni pẹrẹu. Ọpọ wọn ni wọn ba ijakulẹ pade, ti wọn si binu kuro nibẹ laago mejila oru, nigba ti wọn ko ri eyikeyii wọn ko yọju.
Kete tawọn oludije kan ti ṣakiyesi bi nnkan ṣe n lọ lọjọ idibo naa ni wọn ti lahùn, wọn n fapa janu, ti wọn si n ke tantan pe o daju pe eru ati ojooro ti wọ ọrọ eto idibo ọhun.
Paroparo bii ọja ijẹta ni gbogbo agbegbe Doomu ti wọn ni awọn ti fẹẹ ṣe akojọpọ awọn esi idibo naa da titi akọroyin wa fi kuro ni gbọngan ọhun ni nnkan bii aago mẹfa idaji ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹrin.
Aago meje alẹ kọja diẹ ni Ododo atawọn ọmọ igbimọ rẹ too yọju si gbọngan aṣa Doomu, o si to bii wakati kan aabọ ti wọn ti de ki wọn too bẹrẹ ohun ti wọn ni awọn waa ṣe nibẹ.
Ninu ijọba ibilẹ mejidinlogun, mẹrindinlogun ni Ayedatiwa ti wọle, ti Oluṣọla Oke si rọwọ mu nijọba ibilẹ kan ṣoṣo, iyẹn ijọba ibilẹ Ilajẹ, nibi ti oun ati gomina ti jọ wa. Ko si eto idibo nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, nitori rogbodiyan to suyọ nibẹ nigba ti wọn fẹẹ maa dibo.
Lẹyin ti wọn ka gbogbo rẹ tan pata, ibo ẹgbẹrun mejidinlaaadọta ati okoolenigba din meji (48,218) ni Ayedatiwa nikan ni to si ṣe bẹẹ fẹyin awọn alatako rẹ balẹ.
Nigba to n sọrọ lẹyin idibo abẹle ọhun, Gomina Ayedatiwa toun naa jẹ ọkan ninu awọn oludije funpo gomina ọhun sọ pe kan ayọ lo jẹ fun mi nigba ti mo ri i b’awọn eeyan mi ṣe jade lati kopa ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ wa. Ọpẹ ni mo n da lọwọ gbogbo awọn ti wọn fara wọn jin fun aṣeyọri igbesẹ to lapẹẹrẹ yii.
Olori ayọ mi ni pe Ọlọrun tun fun mi lanfaani lati pada wa siluu abinibi mi ni Obe-Nla, gẹgẹ bii oludije to fẹẹ lọọ ṣoju ẹgbẹ wa ninu eto idibo gomina to n bọ lọna.
Mo n fi asiko yii rọ gbogbo awọn akẹgbẹ mi yooku lati jẹ ka jọ para pọ, ka si jọ fi imọ ṣọkan lori bi ipinlẹ Ondo yoo ṣe tẹsiwaju.
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party naa ko gbẹyin ninu awọn to bẹnu atẹ lu aiṣedeedee to waye ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ All Progressive Congress ti ipinlẹ Ondo.
Alukoro ẹgbẹ ọhun, Kennedy Ikantu Peretei, ninu atẹjade ti oun naa fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin yii ni, iwa itiju patapata ni fawọn aṣaaju ẹgbẹ APC bi wọn ṣe foju awọn oludije wọn gbolẹ lẹyin ti wọn gba owo to to bii ojilelẹgbẹrin din mẹwaa miliọnu (#830m) lọwọ wọn gẹgẹ bii owo fọọmu.