Ayedatiwa di Adele-Gomina Ondo, o ni ko sewu lori ilera Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa  ti bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bíi Adele gomina l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa yii.
Ọkùnrin to wa lati agbegbe Ilajẹ, lẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ondo ọhun sọrọ,  ilẹ kun ninu atẹjade kan ti oun funra rẹ fọwọ́ si, eyi to fi ṣọwọ sáwọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee.
O ni ko si òótọ́ kankan ninu ariwo táwọn kan n pa lori bi nnkan ṣe n lọ ninu eto ìṣàkóso ijọba ipinlẹ Ondo.
Ayedatiwa ni aifarabalẹ pẹlu ainisuuru to awọn araalu lo ṣokunfa ahesọ to n waye pe aigbọra-ẹni-ye wa laarin awọn igbimọ aṣẹjọba.
Àwọn ahesọ naa lo ni ko ṣẹyin awọn ọta ìlọsíwájú ilu kan ti wọn fidi-rẹmi lasiko eto idibo abẹle ti wọn ṣe kọjá. O ni oun mọ pe ṣe ni wọn mọ-ọn-mọ n máa sọ isọkusọ yii lati da omi alaafia ipinlẹ Ondo to ti n toro ru.
O ni eto isakoso ipinlẹ Ondo ko figba kankan wọlẹ rara, nitori awọn ipilẹ rere ti ọga oun ti fi lélẹ̀ tẹlẹ. Ó ni ọrọ iṣakoso ijọba gbígbé fun ni ko jẹ tuntun si Aketi gẹgẹ bii ogbontarigi amofin, nitori ki i ṣe igba akọkọ rẹ ree ti yoo gbe ijọba fun oun bii Adele, bẹẹ ni ko sẹni ti ko le ṣàìsàn, níwọ̀n igba tí eeyan ki i ṣe áńgẹ́lì.
Adele-Gomina ọhun ni ki i ṣohun to fara sin pe ṣe ni wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ifilọlẹ ile-igbimọ aṣofin ẹlẹẹkẹwaa, ti awọn aṣofin ko si le ṣohunkohun lasiko ti wọn ba lọ fun aaye ìsinmi wọn.
O waa bẹ awọn eeyan ipinle Ondo kí wọn túbọ̀ maa fi adura rán Arakunrin lọwọ, ki Ọlọrun dawọ lé e, ki ara rẹ tete ya, ko si waa tẹsiwju awọn iṣẹ rere rẹ to n ṣe lọ́wọ́. Bákan naa lo rọ awọn oloṣelu ki wọn kiyesara lori ohun ti wọn aa  máa fẹnu wọn sọ.
Ayedatiwa ni ijọba yoo maa tẹsiwaju ninu akitiyan rẹ lori pipeṣe aabo to peye fáwọn araalu, nitori lara ojúṣe ijọba to ṣe koko ju lọ ni lati daabo bo ẹmí ati dukia awọn ti wọn n dari.
O ni lórúkọ ọga oun loun n dupẹ lọwọ awọn araalu fun adura àti aduroti wọn, o rọ wọn lati tẹsiwaju pẹlu bi ijọba ṣe ń ṣiṣẹ takuntakun lori igbe ayé irọrun wọn.

Leave a Reply