Ayẹyẹ kan ni olukọ KWASU yii n lọọ dari lati Ilọrin to fi ku sinu ijamba ọkọ lọna Eko 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọmowe Ayọtunde Alao lo ti kagbako iku ojiji lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to lọ yii, nigba to n rin irin-ajo lati ilu Ilọrin lọ si ipinlẹ Eko, lati lọọ dari ayẹyẹ kan.

Alao jẹ olukọ nileewe giga Fasiti KWASU, niluu Malete, nipinlẹ Kwara, o si tun maa n tukọ eto lawọn ayẹyẹ gbogbo. Awọn eeyan a maa sọ pe oun ni ẹni ti yoo gba oye imọ ijinlẹ Ph.D, ti yoo si tun maa tukọ eto lode ayẹyẹ gbogbo (MC).

Ọkunrin naa pẹlu Bobby Jay, to jẹ adẹrin-in poṣonu ati awọn mẹta miiran ni wọn jọ n rin irin-ajo lọ siluu Eko ninu ọkọ ayọkẹlẹ wọn.

Itosi Sagamu ni wọn ti ni ijamba mọto, ti ọkunrin naa si ku, ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni awọn mẹta to wa laaye paapaa ṣi wa bayii.

Leave a Reply