Ayẹyẹ Ọdun Ọlọjọ bẹrẹ, Ọọni Adeyẹye wọ Ilofi lọn’Ileefẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lara awọn eto to wa fun imurasilẹ ọdun ọlọjọ to maa n waye lọdọọdun niluu Ileefẹ, Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti wọ Ilofi lalẹ ọjọ Aikum Sundaym ọsẹ yii.

Ọjọ meje ni yoo lo nibẹ lati maa ba awọn alalẹ sọrọ lai gbalejo kankan.

Nigba to n lọ, o ba awọn oniroyin sọrọ, Ọọni sọ pe nnkan meji loun yoo dojukọ lọdun yii. Akọkọ ni lati dupẹ lọwọ Ọlọrun pe arun Korona ko run wa lorileede yii.

Ekeji si ni lati gbadura pe ki Ọlọrun ko si awọn oloṣelu wa ninu lati bẹrẹ si i ṣe nnkan to tọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Awọn oloṣelu wa, ọkan naa ni wọn, mo fẹẹ lọọ ba awọn alalẹ sọrọ, ki wọn jọwọ, ki wọn ri i pe wọn ni ifẹ aiṣẹtan awa ọmọ orileede yii lọkan.

“Ki wọn jọwọ, ki wọn ṣe nnkan to yẹ ki wọn ṣe, akoko n lọ, ilu o gbọdọ daru, ki Ọlọrun Olodumare lọra ẹmi wa lorileede yii.

“Ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo la ni lorileede yii, ṣe ni awọn oloṣelu wa kan n fo lati ẹgbẹ kan si ekeji nitori ipo ti wọn n wa, ko si iyatọ kankan ninu iwa ati iṣe wọn.

“Ṣe la n tan ara wa ti a ba n fi oju ọtọọtọ wo wọn, ṣe ni gbogbo wọn n sa lọ sinu ẹgbẹ to ba wa lode, ṣugbọn orileede Naijiria ga ju wọn lọ.

“Mo n lọ si Ilofi lati bẹ Ọlọrun si wọn, ki wọn yee fi aye wa ta tẹtẹ mọ, o ti to asiko fun wọn lati bẹrẹ si i ṣe nnkan to tọ, a ko le maa tẹ siwaju bi a ṣe n ba a lọ yii”

Leave a Reply