Ayẹyẹ ọjọọbi aadọrin ọdun: Awọn eeyan rọjo adura le Tinubu lori

Faith Adebọla

Latigba ti ọjọọbi Oloye Bọla Ahmed Tinubu, adari apapọ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ti sun mọle lawọn ololufẹ eekan oloṣelu ilu Eko naa ti n palẹmọ ayẹyẹ, bawọn mọlẹbi rẹ ṣe n mura, bẹẹ lawọn mọlẹbi rẹ lagbo oṣelu, lagbo iṣowo, ati lagbo awọn onṣejọba n sọrọ nipa rẹ.
Ko le ma ri bẹẹ, akọkọ ni pe Tinubu ki i ṣe eeyan kerere. Ajanaku kọja mo ri nnkan firi, ta a ba ri erin, ka sọ pe a ri erin ni. Ọdun mẹjọ gbako lo fi jẹ gomina ipinlẹ Eko, lasiko tawọn ologun gbejọba silẹ fawọn oloṣelu lọdun 1999.
Bakan naa ni Tinubu ti re ọpọ awọn ọjẹwẹwẹ oloṣelu dagba, o kọ wọn niṣẹ oṣelu, oun lo si wa lẹyin bi wọn ṣe di olookọ, ti wọn wa nipo nla.
Ohun mi-in to jẹ kọjọọbi tọdun yii tun yatọ ni pe ayẹyẹ aadọrin (70) ọdun loke eepẹ ni. Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, layẹyẹ naa bọ si, tilu-tifọn ni wọn si maa n ṣe e lọdọọdun, ti aadọrin ọdun yii si maa legba kan si tatẹyinwa.
Ayẹyẹ naa si tun bọ sasiko ti Tinubu wa lẹnu erongba ati ilakaka rẹ lati di ẹni akọkọ lorileede yii, o fẹẹ di aarẹ, o si ti n lọ kaakiri lati ba awọn eeyan pataki pataki to gbagbọ pe wọn maa ṣiṣẹ foun lasiko ti ibo sipo aarẹ yoo waye lọdun 2023.
Nileegbimọ aṣofin Eko, odidi ijokoo ati apero akanṣe kan lawọn aṣofin ogoji naa fi peri Tinubu lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta. Wọn pe gomina lati waa ba wọn sọrọ, wọn si pe awọn sọrọsọrọ mi-in lati da wọn lẹkọọ lori ohun to tumọ si pe keeyan jẹ ẹni nla.
Ninu ọrọ ikini ti Aarẹ Muhammadu Buhari fi sọwọ si i latẹnu akọwe iroyin rẹ, Fẹmi Adeṣina, o gboṣuba fun ipa rere ti ọkunrin naa ti ko lagbo oṣelu, ọrọ-aje ati idagbasoke Naijiria. “Apẹẹrẹ atata ni Tinubu to ba dọrọ keeyan jẹ akinkanju, adari, olori, keeyan ṣejọba rere, ati keeyan jẹ ẹlẹyinju-anu.”
Ahmed Lawan, olori awọn aṣofin apapọ sọ ni tiẹ pe, “Tinubu fi eyi to pọ ju laye ẹ sin awọn araalu ni, olulana ni lagbo oṣelu, olori tawọn olori n wari fun si ni. Mo ba Jagaban Borgu yọ, ẹmi ẹ yoo ṣe pupọ loke eepẹ o.”
Fẹmi Gbajabiamila, olori awọn aṣoju-ṣofin, ni ipa ti Tinubu n ko lori ọrọ Naijiria, ateyi to maa ko lọjọ iwaju, ki i ṣe kekere.
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, Olori awọn aṣofin Eko, Mudaṣiru Ajayi Ọbasa, Alaga ẹgbẹ awọn gomina Naijira to tun jẹ gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, Gomina Kogi, Yahaya Bello, t’Ogun, Dapọ Abiọdun, Alaga ẹgbẹ APC apapọ ati ti ipinlẹ Eko, gbogbo wọn ni wọn sọrọ iwuri nipa Aṣiwaju ilu Eko, Tinubu. Iyawo rẹ, Yeye Aṣiwaju ilu Eko, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu, ki ọkọ ẹ pẹlu oṣuba ni. Aka-i-ka-tan si lawọn aṣofin, awọn olokoowo atawọn afẹnifẹre, ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati lẹni kọọkan, ti wọn ki i kuu oriire, ti wọn si ṣadura fun Tinubu pe Ọlọrun yoo lọra ẹmi ẹ.

Leave a Reply