Ayọ abara-tin-in-tin, Olori Timi ilu Ẹdẹ bi ibeji lantilanti

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Sẹnken ni inu Timi ti ilu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Dokita Munirudeen Adeṣọla Lawal, Laminisa 1, n dun bayii pẹlu bi Ọlọrun ṣe fi ibeji ta idile rẹ lọrẹ lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Ọkan lara awọn olori ọba, Olori Aishat Ọmọwunmi, lo bi awọn ọmọ tuntun yii. Obinrin kan, Mariam, ni Olori to jẹ iyawo keji laafin kabiyesi yii ti kọkọ bi, ko too waa bi awọn ibeji to jẹ ọkunrin kan, obinrin kan yii.

Lati wakati ọhun si ni awọn afẹnifẹre ti n wọ lọ saafin kabiesi lati ba baba yọ ayọ ọmọ tuntun yii.

Leave a Reply