Ayọ Adebanjọ kilọ fun Tinubu: Awọn ara Oke-Ọya ko ni i dibo fun ọ

Gbenga Amos, Abẹokuta

Gbogbo ẹni to ba moju oludije sipo gomina lorukọ ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ki wọn tete sọ fun un pe ko waa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Labour, nitori awọn Hausa ko ni i gbejọba fun un, wọn ko si ni i dibo fun un. Baba agba olori awọn ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ayọ Adebanjọ, lo sọrọ yii lọjọ Eti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Keji, ọdun yii, lasiko ipolongo ibo ẹgbẹ oṣelu Labour to waye niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun. O ni ki Tinubu ma wulẹ dojuti ara rẹ nipa kikopa ninu eto idibo yii, ko yaa tete pa a ti.

Nigba to n sọrọ ni Ake Palace ground, to wa niluu Abẹokuta, nibi eto ipolongo ibo Peter Obi ati igbakeji rẹ, Yusuf Baba Ahmed-Datti, ni baba naa ti sọ pe awọn ẹya ilẹ Hausa ti ọkunrin oloṣelu naa gbẹkẹle yoo ja a kulẹ lasiko eto idibo to ti n kanlẹkun yii. O waa rọ gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa lati gbagbe erongba rẹ lati di aarẹ, ko waa ṣatilẹyin fun Peter Obi ko too pẹ ju fun un.

Baba Adebanjọ, ẹni ti awọn agbaagbaa ẹgbẹ naa bii Sẹnetọ Okunrohunmu tẹle wa sibi ipolongo naa ni, ‘‘Gbogbo ẹni to ba moju Tinubu ko sọ fun un, mo ti sọ fun un tẹlẹ, mo si tun n sọ fun un bayii pe awọn ara Oke-Ọya ko ni i dibo fun un. Imọran mi fun Tinubu ni pe ko tete pada wale, ko waa ṣatilẹyin fun Peter Obi, nitori nigba ti eto idibo naa ba pari, ti wọn ba ja a kulẹ, ko ni i ni igboya lati pada wa sile, bo tilẹ jẹ pe to ba pada wa sile naa, a ṣi maa dariji i ti a maa gba a pada’’.

Baba Adebanjo ṣapejuwe ẹgbẹ oṣelu Labour gẹgẹ bii ẹgbẹ NADECO tuntun, o ni awọn ti awọn n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ Labour yii ni awọn ni erongba rere fun awọn eeyan Naijiria, awọn fẹ ki Naijiria dara si i, ka si gba ara wa silẹ lọwọ awọn ijọba alagbara to n mu wa sin.

Nigba to ṣabẹwo si aafin Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ Labour, Peter Obi, naa sọ pe orileede yii ni eto aabo ilẹ rẹ ti buru ju lọ lagbaaye, nitori awa kọ ni a n ṣe akoso ilẹ wa mọ bayii. O waa ṣeleri pe bi wọn ba yan oun sipo aarẹ, oun yoo mojuto eto ẹkọ, oun si ni ohun to pe fun lati yọ awọn eeyan Naijiria kuro ninu iṣẹ ati oṣi lai ya kọbọ lọwọ ẹnikẹni. Obi ni oun ti ṣe eleyii nigba ti oun n ṣe gomina nipinlẹ Anambra, oun si tun le ṣe ju bẹẹ lọ lasiko yii.

Oludije sipo aarẹ yii ni, ‘‘Ipinnu wa ni lati ni Naijira tuntun, a nilo eeyan to ni igboya, to si kun oju oṣuwọn fun iṣẹ to wa niwaju. Eto idibo ọdun 2023 yii ṣe pataki fun wa gan-an ni, a ko gbọdọ jokoo tẹtẹrẹ pẹlu awọn ti ko kun oju oṣuwọn, a fẹ awọn eeyan ti yoo fi ara wọn ji, iṣẹ yii si pe fun ki eeyan ni okun ati agbara, ki ọpọlọ rẹ si pe ṣamuṣamu. Emi ati igbakeji mi ti mura silẹ gidigidi fun iṣe yii ati ohun to pe fun.

Leave a Reply