Ayọdeji ti jẹwọ o: Latigba ti ọmọ mi ti wa ni ọdun meje ni mo ti n ba a lo pọ, iṣẹ eṣu ni

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Baale ile kan to tun jẹ ọdẹ aṣọde, Arowolo Ayọdeji, ẹni ọdun marundinlọgọta (55), ti n ṣẹju pako ni ahamọ ajọ ẹṣọ alaabo sifu difẹnsi ni Kwara, bayii. Ọmọ bibi inu rẹ, ẹni ọdun mọkandinlogun, lo fipa ba lo pọ, lẹyin tọwọ tẹ ẹ lo ni iṣẹ eṣu ni.

L’Ọjọ Ẹti, Furaidee, opoin ọsẹ to kọja yii, ni ajọ sifu difẹnsi ni Kwara safihan baale ile ti wọn ni o n ṣe yunkẹ-yunkẹ pẹlu ọmọ bibi inu rẹ ọhun, leyii ti ko ba ofin mu. Afurasi naa jẹwọ pe loootọ ati lododo ni oun fipa ba ọmọ oun lo pọ, ati pe lati igba ti ọmọ naa ti wa ni ọmọọdun meje loun ti bẹrẹ si i fipa ba a lopọ.

Ayọdeji jẹ ọmọ bibi Ipoti Ekiti, nipinlẹ Ekiti, ṣugbọn to n gbe ni ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. A gbọ pe oun pẹlu obinrin to bi ọmọ to n fipa ba lo pọ yii ti ja, ti igbeyawo wọn ti tuka tipẹtipẹ.

Agbẹnusọ ajọ sifu difẹnsi, Ọlasukanmi Ayeni, sọ pe ileeṣẹ to n ri si irọrun awọn araalu (Social Welfare), ni Kwara, lo mu ẹsun afurasi naa lọ si olu ileeṣẹ ajọ sifu difẹnsi, ti wọn si ṣe akitiyan bi ọwọ ṣe tẹ ẹ, ti wọn si lọọ mu un nijọba ibilẹ Ijero Ekiti, nipinlẹ Ekiti, ti wọn gbe e wa si Ilọrin, nibi to ti ba a lo pọ gbẹyin.

O fi kun un pe lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii, ajọ naa yoo gbe igbesẹ to kan lori iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply