Azeez niyawo oun n yan ale, lo ba lu u pa toyun-toyun ni Ṣaki

Faith Adebọla

Ẹlẹkọ ọrun ti polowo iku ojiji fun obinrin alaboyun kan, Abilekọ Nimọta Giwa, niluu Ṣaki, lagbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, ọkọ rẹ, Ọgbẹni Azeez Giwa, la gbọ po fibinu ki obinrin naa mọlẹ, ko tiẹ ro ti pe o diwọ disẹ sinu, o lu u bii ẹni lu baara debii pe obinrin naa dagbere faye lẹyin wakati mẹta ti alubami naa waye.

Owurọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niṣẹlẹ ọhun waye laduugbo Sango, niluu Ṣaki. A gbọ pe lati ọjọ Satide ni ede aiyede kan ti bẹ silẹ laarin tọkọ-taya yii, ọrọ nipa oyun tiyawo naa ni ni wọn lo dija, wọn lọkọ sọ pe oun kọ loun loyun, ti wọn si bẹrẹ si i ṣe gbolohun asọ titi tọrọ naa fi di nla mọ wọn lọwọ.

Wọn lawọn agbaagba adugbo to wa nitosi da sọrọ naa lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, nigba ti wọn tun gburoo ariwo Nimọta ati ọkọ rẹ, ti wọn si rọ awọn mejeeji pe ki wọn bomi suuru mu, ki wọn lọọ sun.

Bi ilẹ ṣe mọ ni wọn ni ija ọhun tun burẹkẹ laarin wọn, wọn ni ibinu gidi ni baale ile naa ba ji, lo ba ki iyawo ẹ mọlẹ, o si bẹrẹ si i lu obinrin naa nilukilu.

Iṣẹlẹ yii ni wọn lo mu kawọn eeyan to ja Abilekọ yii gba lọwọ ọkọ ẹ sare gbe e digbadigba lọ sileewosan aladaani kan to wa niluu Ṣaki, latari bi obinrin ṣe n kigbe irora pẹlu oyun ninu, awọn nọọsi ati dokita ọsibitu naa si bẹrẹ si i sare lati doola ẹmi ẹ.

Nnkan bii wakati mẹta lẹyin ti wọn n fun Nimọta ni itọju iṣegun yii lawọn dokita kede pe o papa dakẹ.

Boya ẹnikan ti ta abẹṣẹẹku-bii-ojo Azeez yii lolobo ni o, boya ara lo si fu u, wọn lọkunrin naa ti dawati nile to n gbe, o ti sa lọ, ṣugbọn awọn mọlẹbi oloogbe ti lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa, awọn agbofinro si ti n wa a kiri bayii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọyọ ko ti i le fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ko ti i gbe ipe rẹ titi dasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ṣugbọn Ọgbẹni Oluwọle, ọlọpaa to n ṣiṣẹ pẹlu teṣan Ṣaki sọ pe ootọ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, o lawọn mọlẹbi iyawo naa ti waa fi ọrọ naa to awọn leti, wọn si ti lọọ gba oku ẹni wọn lati lọọ sin in, ati pe awọn ṣi n wa afurasi ọdaran naa ti wọn lo ti na papa bora bayii.

Leave a Reply