Azikiwe bori awọn ọta ẹ, o loun yoo di aarẹ alagbada ni 1979 ṣaa ni

Ọlayiwọla Alaga

Ni ọjọ kejilelogun, oṣu karun-unm 1979, ẹsẹ ko gbero ni ile-ẹjọ giga ipinlẹ Anambra igba naa, gẹgẹ bi Adajọ Araka ti ṣe sọ. Ọjọ naa ni wọn fẹẹ mọ ibi ti ẹjọ ti Oloye Nnamdi Azikiwe to fẹẹ du ipo aarẹ Naijiria lorukọ ẹgbẹ oloṣelu NPP yoo fori sọ. Ohun to faja ni pe wọn ni Azikiwe ko gba iwe owo-ori lasiko to yẹ ko gba a, Azikiwe ni oun gba iwe owo-ori oun pe perepere, nigba tawọn FEDECO to n ṣeto ko si fẹẹ fi orukọ baba naa silẹ, tabi ki wọn fun un ni ohun to tọ si i, n lo ba gba ile-ẹjọ lọ. O pe Michael Ani ti i ṣe olori FEDECO lẹjọ, bẹẹ lo si pe ijọba apapọ naa, o ni ki wọn waa ro tẹnu wọn niwaju adajọ, ki oun le mọ bo ba jẹ oun jẹbi tabi loootọ loun jare. N ni Adajọ Araka ba fi igbẹjọ si ọjọ kejilelogunm oṣu karun-un, ọjọ naa si lẹjọ ọhun bẹrẹ loootọ. Ero bii omi, wọn ti Eko wa, wọn ti Ibadan wa, awọn ero lati ilẹ Hausa ko si niye.

Nigba ti ẹjọ naa bẹrẹ nile-ẹjọ yii, Azikiwe funra ẹ lo kọkọ rojọ, ṣe waa-wo-o ni i kọkọ ri i. Azikiwe ni ki ile-ẹjọ wo olori FEDECO, Michael Ani, to n ṣeto idibo yii daadaa, o lo fẹẹ fi ẹmi oun wewu ni, idi to si fi n ṣe bẹẹ ko ye oun. Baba naa ni lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kejila, ọdun 1978, wọn pe oun si ipade kan ni Baraki Dodan ti awọn ologun ti n ṣejọba wọn. O ni ọrọ lori idibo to n bọ lawọn jọ sọ nibẹ, ẹni to si ṣe alaga ipade awọn yii ni Ọgagun Agba Shehu Musa Yar’Adua. Azikiwe ni nibi ipade naa ni awọn ti fẹnu ko pe gbogbo ẹni to ba fẹẹ du ipo aarẹ, wọn yoo ṣeto aabo to peye fun un: wọn yoo fun un ni ọlọpaa ati awọn agbofinro mi-in ti yoo maa ṣọ ọ kaakiri. O ni lẹyin ipade naa, oun gba lẹta latọdọ ọga ọlọpaa pata to fi sọ foun pe oun wa ninu ẹni ti awọn yoo pese eto aabo fun, awọn n reti iwe lati ọdọ FEDECO ni.

Azikiwe ni kaka ki FEDECO kọ iwe si awọn ọga ọlọpaa pe ki wọn fun oun ni ọlọpaa ti yoo maa tẹle oun kiri bi oun ti ṣe n kampeeni, niṣe ni wọn kọwe soun pe oun ko le ri eto aabo kan lati ọdọ awọn ọlọpaa nitori oun ko san owo-ori to yẹ ki oun san. Baba oloṣẹlu naa ni ohun to n dun oun ju ninu ọrọ yii ni pe oun sanwo ori, oun san awọn owo naa, o si pe perepere. O ni loootọ ni ọrọ owo-ori naa ni bakan ninu, ṣugbọn ki i ṣe lati ọdọ oun, lati ọdọ awọn ti wọn n ṣeto owo-ori ti wọn bu iye ti ko yẹ ki oun san foun ni. O ni loju ẹsẹ ti wọn ti bu owo naa foun loun ti kigbe sita fun wọn, ti oun si ti kọwe lati fi gbe ọrọ oun nidii pe wọn ṣi owo ṣe foun. Azikiwe ni pẹlu ẹ naa, oun san iye kan, pe nigba ti wọn ba si yanju ọrọ naa tan, oun yoo waa san iye to ku, bi wọn si ti ṣe yanju ọrọ naa tan loun ti san iye to tọ soun.

Aminu Kano

Ọkunrin ti yoo du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ PP naa ni, nigba ti alara ba waa ni ara ko roun, ti awọn ti wọn n gba owo-ori ko sọ pe oun ko san owo-ori oun, kin ni ti FEDECO to fẹẹ ṣeto ibo lati maa tọpinpin oun; pe oun sanwo ori tabi oun ko san. O ni ohun to jẹ koun wa sile-ẹjọ ree o, oun fẹẹ ki ile-ẹjọ gba oun, boya FEDECO lẹtọọ lati fi ẹmi oun wewu tabi wọn ko lẹtọọ o. Bo ti sọrọ tan ni agbẹjọro awọn FEDECO, to tun jẹ agbẹjọrọ agba fun ijọba  apapọ, M.O Ṣoẹtan, fo dide, o ni ki Azikiwe ma gbe ọrọ bẹẹ yẹn wa, ko ma fi ọrọ didun tan awọn eeyan jẹ. O ni ko si igba kankan ti FEDECO sọ pe Azikiwe ko san owo-ori, ohun tawọn sọ ni pe lasiko ti ibo n bọ lo lọọ sare san owo-ori ẹ, eleyii ko si ba ofin idibo to n bọ yii mu. Ṣoẹtan ni ki Adajọ Araka beere lọwọ Azikiwe boya o sanwo ẹ nigba to yẹ ko san an.

Ṣoẹtan ni bi ofin ba sọ pe ki eeyan san owo-ori ẹ nigba to tọ ati igba to yẹ, iyẹn ki i ṣe pe ko ko risiiti wa pe oun ti sanwo ori oun, ofin gbọdọ yẹ ẹ wo pe ṣe igba to tọ ati igba to yẹ lo san owo naa, pe ohun ti awọn n tori ẹ ba Azikiwe ja niyẹn. “Ohun ti ofin idibo wi ni pe ẹni to ba fẹẹ du ipo aarẹ gbọdọ ti san owo-ori rẹ nigba to tọ ati igba to yẹ. Ohun ti awa di mu niyi, nitori ohun ti ijọba apapọ to ṣe ofin fẹ niyẹn. A gbọdọ yẹ gbogbo ofin wo ka too gbe idajọ kankan kalẹ lori ọrọ yii, nitori bi a ba ni a fẹẹ ṣe oṣelu, tabi pe a fẹẹ di ipo nla mu lawujọ, awọn iwa kan wa ti wọn gbọdọ ba lọwọ eeyan, iwa naa gbọdọ jẹ ti ọmọluabi, ko si ta ti awọn eeyan awujọ yọ” Ṣoẹtan lo n sọrọ bẹẹ, o ni ohun ti awọn fẹ fun Azikiwe to fẹẹ du ipo aarẹ ree, ki i ṣe ko ko risiiti wa pe oun sanwo ori, nigba to jẹ owo-ori to san, o san an nitori o mọ pe oun fẹẹ du ipo aarẹ ni.

Jaja Wachukuwu ko jẹ ko sọrọ naa tan ti oun paapaa fi foyinbo nla da a lohun, ṣe Wachukwu yii ni lọọya Azikiwe. O ni gbogbo ohun tawọn FEDECO n sọ yii, misiteeki ni wọn n ṣe. O ni Azikiwe sanwo ori ẹ, gbogbo risiiti to wa niwaju wọn si fi han pe o sanwo. Ṣugbọn misiteeki ti wọn n ṣe ni pe wọn ro pe ọjọ ti wọn ri lori risiiti yii lo ṣẹṣẹ sanwo, wọn ko mọ pe ọjọ ti wọn yanju wahala to wa lori ọrọ owo-ori ẹ ni, pe deeti tawọn olowo-ori naa kọ sara risiiti ki i ṣe deeti ọjọ ti Azikiwe sanwo fun wọn, igba ti ọrọ yanju ni.O ni gbogbo awọn ibi ti wọn fi inki pupa kọwe si yẹn ki i ṣe ohun ti adajọ tabi ẹnikẹni gbọdọ tẹle, nitori awọn deeti ti ki i ṣe ọjọ isanwo ni. N loun naa ba bẹrẹ si i fi iwe han adajọ, o ni ki wọn wo o, Azikiwe sanwo ori nigba bayii, o tun san an nigba bayii, ṣugbọn deeti ọtọ ni awọn olowo ori kọ si i.

Jaja Wachukwu yii ni bi a ba tilẹ fẹẹ da a silẹ ka tun un ṣa, ọrọ ti ko kan awọn FEDECO ni wọn n tori ẹ fapajanu yii. O ni awọn kọ ni wọn gba owo-ori, wọn ko si le mọ ẹni to san owo-ori nigba to yẹ tabi nigba ti ko yẹ. O ni ki ọrọ ma di ariwo, ki wọn mu ọga awọn olowo ri wa, oun ṣi fẹ ko waa ṣalaye ọrọ naa loju gbogbo eeyan. Igba ti ọga awọn olowo ori ti Wachukwu si mu wa, Christopher Nweri, bọ sinu igi lati rojọ, ibeere kan naa ni ọkunrin lọọya to ti figba kan jẹ minisita ni Naijiria yii beere lọwọ rẹ, o ni, “Ẹ jọwọ, ṣe Oloye Azikiwe san owo-ori fun ọdun 1976 si 1977 abi ko san an?” Niyẹn naa ba dahun, o ni Azikiwe sanwo ori ẹ nigba to tọ ati nigba to yẹ. Ni Wachukwu ba ni ko maa lọ, ọrọ ko pariwo mọ. N ni Adajọ Araka naa ba tilẹkun ẹ, o ni bo ba di ọjọ karun-un, ọjọ ti wọn rojọ naa, ki wọn waa gbọ idajọ oun.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu karun-un, 1979, lọjọ naa bọ si, ọjọ Aje, Mọnde, kan bayii ni. Ni Emmanuel Araka ba gori aga idajọ, lo ba dajọ pe Azikiwe san owo-ori ẹ daadaa, FEDECO ko si lẹtọọ lati fi ẹmi ẹ wewu, bẹẹ lo lẹtọọ lati du ipo aarẹ to fẹẹ du lorukọ NPP, ti ko si ṣenikan to gbọdọ tori ọrọ owo-ori da a duro. Adajọ naa tilẹ bu Michael Ani to n ṣeto idibo, o ni iwa to hu ko dara rara. O ni ki lo de to lọọ sọ fun gbogbo aye pe Azikiwe ko ni iwe owo-ori, nigba to jẹ ohun to yẹ ko sọ ni pe oun ko ti i ri risiiti iwe owo-ori ọkunrin naa, ṣugbọn o kan jade lati lọọ ba orukọ rẹ jẹ nita gbangba pe ko ni iwe ori ni. Lọrọ kan ṣaa, nibi ti ọrọ naa ku si ree, Azikiwe gba agbara rẹ pada, yoo si dupo aarẹ pẹlu Ibrahim Waziri ti ẹgbẹ GNPP, Shehu Shagari ti ẹgbẹ NPN, Aminu Kano ti ẹgbẹ PRP ati Ọbafẹmi Awolọwọ ti ẹgbẹ UPN. Ọjọ keje oṣu keje 1979 ni wọn yoo si dibo akọkọ.

Leave a Reply