Ba a ba sọ iwa ibajẹ ta a ri nileeṣẹ mọna-mọna ilẹ wa, omije aa ja bọ loju araalu- Ọga EFCC 

Adewale Adeoye

Ẹni a gboju okun le ko jọ ẹni agba lọrọ ileeṣẹ mọnamọna nilẹ wa. Ba a ba ni ka maa sọ aṣiri awọn iwa ibajẹ to tu sita nileeṣẹ yii lasiko iwadii wa, ọpọ araalu ni yoo bu sẹkun nibi ti nnkan naa buru de. Nitori awọn to yẹ ko maa ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe ohun gbogbo lọ deede nileeṣẹ naa ni wọn n huwa ibajẹ to n pa araalu lara.

Ọga agba ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ wa, iyẹn ‘Economic And Financial Crimes Commission’ (EFCC), Ọgbẹni Ọla Olukayọde, lo sọrọ yii di mimọ lasiko ti igbimọ to n mojuto iwa ibajẹ to ni i ṣe pẹlu eto inawo, (House Committee on Financial Crime), ṣabẹwo si ajọ naa lo sọrọ ọhun di mimọ. Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘’Ọrọ ọhun kọja afẹnusọ, awọn ọbayejẹ ẹda pọ lorileede yii gan-an ni o, ba a ba ki ẹnu b’ọrọ iwa ibajẹ ati magomago ta a ri nileeṣẹ mọna-mọna orileede yii, ọpọ lo maa bu sẹkun! Iwa ibajẹ naa gbilẹ to bẹẹ gẹ to jẹ pe bi wọn ba ni ki wọn lọọ ra awọn ohun eelo lati fi ṣatunṣe sawọn irinṣẹ nileeṣẹ mọna-mọna orileede yii, gbantu-ẹ-yọ ni wọn maa lọọ ra wa, nigba mi-in, awọn kan ko tiẹ ni i ra awọn ohun eelo naa rara, eyi to n ṣakoba fun ina atawọn nnkan mi-in nilẹ wa.

‘’Fun apẹẹrẹ, bi wọn ba ni ki wọn lọọ ra waya tabi irinṣẹ kan to nipọn niwọn ọna mesan-an ‘9.0 gauge’ wa lati fi ṣatunṣe sọrọ ina mọnamọna to n ṣe ṣege-ṣege, ṣe ni wọn aa lọọ ra eyi ti ko daa, wọn le ra to nipọn lọna marun-un ‘5.0 gauge’’.

Bẹẹ ni ko ni i pẹ ti eyi maa fi bajẹ, a waa di pe o n jona nigba gbogbo. Awọn ọbayejẹ yii kan naa ni wọn aa maa sọ kaakiri pe ijọba ko ṣe nnkan kan nipa ina mọnamọna ọhun. Bawọn opo to n gbena wọlu ṣe n figba gbogbo daṣẹ sile lojiji lasiko yii, ara iwa ọdaran tawọn tijọba gbeṣẹ fun n hu lo fa a. Ko si baa ṣe fẹẹ lo irinṣẹ to nipọn lọna marun-un fi rọpo eyi to yẹ ko nipọn lọna mesan-an ti ohun ta a fẹẹ fi ṣe ma dara rara.

O fi kun un pe ọkan ninu awọn ibi ti iwa ibajẹ gogo si ju ni ẹka ileeṣẹ to n pese ina yii, eyi to n ṣẹ akoba fun awọn ohun amayedẹrun nilẹ wa.

O waa rọ awọn araalu lari fọwọsowọpọ pẹlu igbimọ naa atawọn aṣofin lati le gbogun ti iwa ibajẹ lorileede wa.

 

Leave a Reply