Baalẹ fun ara ẹ lominira, niṣe lo sa mọ awọn ajinigbe lọwọ ninu igbo l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Ondo

Awọn eeyan ilu Igasi Akoko to wa ni Ariwa-Iwọ Oorun ipinlẹ Ondo ko le pa idunnu wọn mọra nigba ti wọn gbọ pe olori abule naa, Oloye Ojo Ajaguna, ti jajabọ lọwọ awọn ajinigbe ti wọn ji i gbe, ti wọn si ti n beere owo nla lọwọ awọn eeyan rẹ ṣaaju akoko naa.

ALAROYE gbọ lati ẹnu awọn eeyan ilu naa pe ninu igbo kojikiji kan ni wọn gbe ọkunrin naa lọ lẹyin ti wọn ji i gbe. Ṣugbọn nigba ti awọn ajinigbe yii sun lọ lọkunrin naa dọgbọn sọrọ ara rẹ, lo ba gbe ere da si i ninu igbo ibẹru naa.

Lẹyin ọpọlọpọ wakati, baba naa jade si gbangba, o si pada wọnu ilu naa laaye.

Awọn eeyan ilu naa ko le pa idunnu wọn mọra nigba ti wọn ri oloye yii. Ṣe gbogbo wọn ni wọn ti wa ninu ibanujẹ latigba to ti wa lakata awọn ajinigbe yii. Niṣe ni ariwo sọ, ti gbogbo wọn si fo fayọ pe wọn tun ri ọkunrin naa laaye.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami fidi ẹ mule pe loootọ ni aọn ajinigbe ji oloye naa gbe, ootọ si ni pe o ti gba ominira lọwọ wọn.

O ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii.

Leave a Reply