Baale ile ji foonu meji, oṣu mẹta ni yoo fi gba teṣan ọlọpaa l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi,Abeokuta
Ẹni ọdun mejilelaaadọta ni baale ile kan ti orukọ ẹ n jẹ Usman Abdullahi, ṣugbọn bo ṣe jẹ agbalagba yii lo huwa abuku, foonu meji lo ji lọdọ awọn ẹni ẹlẹni ti ko fura, bi kootu ṣe ni yoo ni lati gba teṣan ọlọpaa foṣu mẹta gẹgẹ bii ijiya ẹṣẹ ẹ niyẹn.
Baba yii funra ẹ jẹwọ ni kootu Majisireeti Iṣabọ ti wọn gbe e wa lọjọ Ẹti to kọja, pe oun wọ ṣọọbu ọkunrin kan, Ibrahim Ogundipẹ, ni Panṣẹkẹ, l’Abẹokuta, lọjọ kọkandinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021.
O loun sọ fun un pe oun fẹẹ ko ba oun ṣe iwe idanimọ (ID Card), nitori iṣẹ ti Ibrahim n ṣe niyẹn. O ni nibi to ti n da awọn kọsitọma mi-in lohun lọwọ loun ti ji Infinix Hot 9 to n lo, ẹgbẹrun mẹrinlelaaadọta naira ni wọn n ta foonu naa.
Olujẹjọ yii tun lọ si ṣọọbu ọkunrin telọ kan, Oluṣẹgun Ọlọrunmade, o ṣe bii ẹni to fẹẹ ranṣọ, bẹẹ ko ni aṣọ kan to fẹẹ ran. Ki ẹni to ni ṣọọbu too da a lohun lo ti ji foonu iyẹn naa mu, Infinix Hot 6 ni ti Oluṣẹgun, ẹgbẹrun mejilelogoji naira ni wọn n ta a.
Ṣugbọn ori ta ko baba to n jale kiri ṣọọbu yii gẹgẹ bi Agbefọba, Lawrence Olu-Balogun, ṣe wi, wọn ri i mu ko too lọ jinna, wọn si ba awọn foonu naa lọwọ ẹ pẹlu.
Nigba to n ṣalaye ara ẹ ni kootu, Usman ni loootọ loun ji awọn foonu naa, ṣugbọn oun ko ni i ṣe bẹẹ mọ, ki Adajọ jọwọ, ṣaaanu oun.
Adajọ Dẹhinde Dipẹolu, paṣẹ pe Usman yoo ṣiṣẹ ilu foṣu mẹta. O ni teṣan ọlọpaa to wa ni Adigbẹ ni yoo lọọ maa gba, ti yoo si maa tun ibẹ ṣe foṣu mẹta gbako.
O fi kun un pe awọn alaboojuto ọgba ẹwọn to wa ni Ibara, ni yoo maa mojuto iṣẹ rẹ naa fun oṣu mẹta ti yoo fi ṣe e. Ki tiẹ yii le jẹ ẹkọ fawọn eeyan to ni ẹmi ole jija bii tirẹ lati ma ṣe dan an wo rara.

Leave a Reply