Baalẹ ilu dero ahamọ ọgba ẹwọn, wọn lọ lu jibiti miliọnu meji naira

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori ti wọn lo lu ẹnikan ni jibiti miliọnu meji naira, baba kan to pera ẹ ni Baalẹ abule Onidundu, Oloye Olagoke Amọo Samson-Onidundu, ti dero ahamọ ọgba ẹwọn Abolongo, niluu Ọyọ.

Ajọ to n gbogun ti magomago owo ati iwa jibiti, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission, (EFCC) lo gbe e lọ si kootu, wọn lo lu ọkunrin kan to n jẹ Oluwagbemi Isaac ni jibiti miliọnu meji naira.

Gẹgẹ bi Isaac ṣe fẹsun kan Baalẹ lọdọ ajọ EFCC, ti ileeṣẹ agbofinro ọhun si ṣalaye nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ilẹ eeka mẹrin lolufisun naa ra lọwọ olujẹjọ. Miliọnu mẹrin ati ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (N4.4M) ladehun owo ti wọn jọ fẹnu ko le lori, ti onitọhun si san idaji ninu owo naa ti i ṣe miliọnu meji naira silẹ lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun to kọja.

Ṣugbon gbogbo igba ti Samson ba ti fẹẹ lọọ ṣabẹwo sori ilẹ yii lawọn kan maa n le e danu bii ẹni le ewurẹ kuro nisọ olounjẹ. Ninu ọrọ ti oun atawọn eeyan naa jọ sọ ni wọn ti fi ye e pe ki i ṣe Oloye Samson lo nilẹ, baba naa kan lu u ni jibiti lasan ni nitori awọn lawọn nilẹ awọn.

Lẹyin ti baba naa ti fiṣẹlẹ yii to Baalẹ leti, ṣugbọn ti ko jọ pe baba oloye naa ri igbese gidi kan gbe lori ẹ, lonitọhun mu ẹjọ ẹ tọ ajọ EfCC lọ.

Ẹsun mẹrin ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu iwa jibiti ni wọn fi kan olujẹjọ, ṣugbọn baba to pera ẹ ni baalẹ yii sọ pe oun ko jẹbi ọkankan ninu wọn.

Lẹyin naa lagbẹjọro ajọ EFCC, Ọmọwe Ben Obi rọ ile-ẹjọ lati sun igbejo naa siwaju ki oun le ko awọn ẹri ti oun ni lati fi ta ko olujẹjọ wa si kootu.

 

Nigba naa l’Onidaajọ Iyabọ Yerima paṣẹ pe ki awọn agbofinro lọọ fi baba oloye si ahamọ ọgba ẹwọn Abolongo to wa niluu Ọyọ, titi di ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 yii, ti igbẹjọ naa yoo bẹrẹ ni pẹrẹu.

Leave a Reply