Olori awọn ṣọja ilẹ wa ku lojiji, ninu ijamba ẹronpileeni lo ku si ni Kaduna

Ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni ajalu nla kan ṣẹlẹ pẹlu bi baaluu ileeṣẹ ologun kan ṣe ja lasiko ti ojo buruku kan n rọ lọwọ ni papakọ ofurufu to wa nipinlẹ Kaduna.

Nibi ti baalu ti maa n fo tabi balẹ si ni ọkọ ofurufu  naa ti ja. Gbogbo awọn mẹjọ to wa nibẹ la gbọ pe wọn ti ku bayii. Olori awọn ṣọja ilẹ wa, Attahiru Ibrahim wa ninu awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Leave a Reply