Baalu ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ilẹ wa ja ni Kaduna

Jọkẹ Amọri
Ni ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni baalu ileesẹ ọmọ ogun ofurufu ilẹ wa (NAF) ja lojiji, to si pa awọn to n wa a meji to wa ninu rẹ. niluu Kaduna.
ALAROYE gbọ pe baalu ti wọn n lo fun ẹkọṣẹ awọn ọmọ ogun ofurufu ilẹ wa ni baalu ọhun to ja niinu ọgba wọn , awọn awakọ ofurufu yii meji to wa ninu rẹ lo si ku.
Iru iṣẹlẹ yii kan naa ṣẹlẹ ninu oṣu Karun-un, ọdun 2012, nibi ti baalu ileeṣẹ ofurufu yii ti ọga ṣọja patapata nilẹ wa lasiko naa, Ibrahim Attahiru atawọn ọmọọṣẹ rẹ wa, ti gbogbo wọn si ku patapata.
Iwadii ti bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa ijamba naa.

Leave a Reply