Baaluu awọn ologun gbina l’Abuja, eeyan mẹfa lo ku

 

Jide Alabi

O kere tan, eeyan mẹfa ni wọn sọ pe wọn padanu ẹmi wọn lasiko ti baluu agberapaa, ti awọn ṣọja n lo gbina niluu Abuja.

Awọn meji kan ti wọn jẹ awakọ baaluu ọhun atawọn mẹrin mi-in la gbọ pe wọn ku ninu iṣẹlẹ ọhun. Ipinlẹ Niger ni wọn sọ pe baaluu ọhun ti gbera, to kọri si Abuja, ki ẹnjinni rẹ too daṣẹ silẹ ni nnkan bii aago mọkanla ku iṣẹju mọkanlelogun laaarọ yii.

Nibi ti awakọ baluu ọhun ti nọmba ẹ jẹ NAF201 B350, ti n gbiyanju lati balẹ si Abuja ni kete to ti ri i pe ẹnjinni ọkọ ofurufu ọhun ti daṣẹ silẹ ni baaluu ọhun ti gbina mọ ọn lọwọ.

Minisita fun ọkọ ofurufu, Hadi Sirika, ninu ọrọ to kọ sori ikanni abẹyẹfo ẹ ti sọ pe, “Ọkọ agberapaa tawọn ologun ti orukọ ẹ n jẹ King Air 350 ti ni ijamba niluu Abuja, lasiko ti awakọ ẹ n gbiyanju lati wa a gunlẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe. Minna, nipinlẹ Niger, ni wọn sọ pe o ti gbera. Ohun ti a si gbọ ni pe ijamba ọhun le pupọ, ṣugb̀ọn mo fẹẹ rọ wa ki a ni suuru titi digba ti abajade iwadii yoo waye.

Ṣa o, ileeṣẹ ẹṣọ ofurufu ko ti i sọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ ọhun.

 

Leave a Reply