Baba Akintoye kilọ fun Tinubu atawọn ẹmẹwa ẹ: Ẹ ma kọyin sibi t’aye kọju si o

Faith Adebọla

Olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oduduwa, ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ ọmọ Yoruba nile loko nni, Ọjọgbọn Banji Akintoye, ti ṣekilọ fun Aṣiwaju Bọla Tinubu atawọn agbaagba ilẹ Yoruba lẹgbẹ APC pe ki wọn jawọ ninu ipinnu to maa ṣediwọ fun ifẹ ọpọ ọmọ Yoruba, tori iru iwa bẹẹ maa sọ wọn di ọta araalu ni.

Baba naa sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi lede lati fi erongba rẹ han lori ipade tawọn agbaagba ilẹ Yoruba ninu ẹgbẹ APC ṣe lọjọ Aiku, Sannde yii, l’Ekoo, atawọn ipinnu wọn.

Lara ipinnu tawọn agbaagba yii fẹnu ko le lori ni pe awọn o fara mọ bawọn kan ṣe lawọn maa ya kuro lara Naijiria, awọn maa da duro, wọn ni iṣọkan ati ilọsiwaju Naijiria lawọn duro fun ni tawọn.

Akintoye sọ pe: “O ṣe ni laaanu pe bi wọn ṣe lawọn o fara mọ idasilẹ Orileede Oduduwa ni tawọn, pe Naijiria yii lawọn rọ mọ, ipinnu to maa mu ki wọn geka abamọ jẹ ni wọn ṣe.

Adura mi ni pe nigba to ba ti jo wọn loju tan, ki Ọlọrun fun wọn lọkan akin ti wọn yoo fi le gba aṣiṣe wọn, ki wọn si yipada.

Lara awọn agbaagba to ṣepade ọhun ni Bọla Tinubu, Oloye Bisi Akande, Femi Gbajabiamila atawọn gomina Eko, Ogun ati Ọṣun, nibi ti wọn ti sọ pe awọn ko fara mọ awọn to n ja fun Orileede Oodua.

Leave a Reply