Baba arugbo kan yinbọn pa ara rẹ, lo ba ku patapata

Adeoye Adewale

Kayeefi lọrọ baba arugbo kan, Oloogbe Kareem Aderemi, ẹni ọdun mejilelaaadọrin (72Yrs), kan to jinbọn pa ara rẹ, to si ku loju-ẹsẹ, nile rẹ to wa, lagbegbe Alapo, niluu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, ṣi n jẹ fawọn eeyan ti wọn gbọ nipa iku baba naa.

ALAROYE gbọ pe ọjọ ti pẹ diẹ ti Kareem ti wa lẹnu aisan buruku kan ti ko fi bẹẹ han sawọn eeyan. Bakan naa lo ni ipenija aisan oju to n yọ ọ lẹnu, eyi ti ko fi le riran daadaa.

Alukoro ajọ Sifu Defẹnsi, ‘Nigeria Security And Civil Defence Corps’  ẹka tilu Ẹdẹ, Abilekọ Kẹhinde Adeleke, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin Punch, lọjo Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, sọ pe Oloogbe Kareem ti wa ninu ailera lati ọjọ pipẹ, ti ko si rẹnikan ṣetọju rẹ. Aisan yii ati airi itọju to peye lo mu ki baale ile naa ro o pin, lo ba yinbọn oloju meji kan to ni ninu ile lu ara rẹ.

Adeleke ṣalaye pe, ‘‘Lọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, la gbọ pe Kareem gba ẹmi ara rẹ pẹlu ibọn oloju meji kan to jẹ tiẹ. Wọn ni ọjọ ti pẹ diẹ ti baba yii ti n koju ipenija ailera ara, bẹẹ ni ko tun riran daadaa. O jọ pe oun nikan lo n gbe inu ile lati ọjọ bii meloo kan sẹyin, nigba to si maa fi di ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, ni Kareem ro o pin, to si ki ibọn bọ ẹnu rẹ lori ibi to jokoo si, lo ba yin in, ọta ibọn ọhun si fọ ọ lẹnu yankan-yankan’’.

Alukoro ọhun ni lara iwadii tawọn ṣe nipa ibi ti Kareem ti ri ibọn to fi pa ara rẹ yii lawọn ti ri ẹri to daju pe Kareem gba iwe aṣẹ fun ibọn ọhun latọdọ ijọba.

Ọkunrin ẹṣọ alaabo yii ni loju-ẹsẹ tawọn ti fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa agbegbe ibi ti Kareem n gbe leti ni wọn ti lọ sibi to ku si, ti wọn si mu ibọn naa lọ si teṣan wọn. Bakan naa ni wọn ti n ṣeto bi wọn yoo ṣe sinku Oloogbe bayii.

Leave a Reply