Jọkẹ Amọri
Aṣaaju ẹsin Musulumi kan, Aafaa AbdulWahab Fọlọrunṣọ Ọlaitan ati baba rẹ, Suleiman Babatunde Ọlaitan lẹwọn ọdun mẹrin ati oṣu mẹrin. Ẹsun hiwu oku Suleiman Saka, ti wọn si tun ba ẹya ara oku ọhun lọwọ wọn, ni wọn jẹbi ẹ.
Ile-ẹjọ Majisreeti kan to wa niluu Ilọrin lo gbọ ẹjọ wọn, to si ṣedajọ wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee yii.
Lara ẹsun ti wọn fi kan baba atọmọ naa niwaju Adajọ Bio Salu ni pe wọn gbimọ-pọ lati huwa buruku, wọn huwa ọdaran lori ilẹ onilẹ, ati pe wọn ba ẹya ara eeyan lọwọ wọn lọna aitọ. Awọn ẹsun wọnyi ta ko isọri kẹtadinlọgọrun-un (97), okoolerugba o din ẹyọ kan (219), ati ojilelọọọdunrun le meji (342) iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Kwara.
Gẹgẹ bii abọ iwadii tawọn ọlọpaa ṣe, wọn ni Alaaji Aliyu Baba Alapa to n gbe agboole Onilu, lagbegbe Oloje, niluu Ilọrin, lo waa fẹjọ awọn ọdaran naa sun lẹka ileeṣẹ ọlọpaa Area ‘G’ lọdun 2018, wọn loorun buruku to n bu jade latinu yara tawọn eeyan yii tọju oku olokuu ti wọn lọọ ji hu pamọ si lo fu awọn aladuugbo lara ti wọn fi bẹrẹ si i wa ibi tooorun buruku naa ti wa, laṣiiri ba tu.
Ori eeyan kan, ọwọ meji, ẹsẹ meji ti wọn ko sinu ike kan lawọn ọdaran naa tọju soke aja ile wọn, nigba ti awo ya.
Awọn ọlọpaa ni iwadii fihan pe ki i ṣe awọn meji yii nikan lo ṣiṣẹ buruku ọhun, awọn ẹmẹwa wọn marun-un mi-in ti sa lọ, pẹlu iyooku ara oku naa ti wọn gbe sa lọ ninu ọkọ ayọkẹlẹ Honda Accord kan.
Orukọ awọn yooku tọlọpaa ṣi n wa ni Ọladimeji, AbdulWahab, Jẹlili ati Waidi, Wọn lọwọ ti ba Ọgbẹni Ajuwọn laipẹ yii nibi to ti n sa kiri nipinlẹ Ogun, oun naa si ti jẹwọ pe loootọ loun lọwọ ninu iwa ọdaran ọhun.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ ki-in-ni, oṣu kẹjọ, ọdun 2017, ni wọn huwa ọdaran yii. Ọrẹ timọtimọ ni wọn pe Saka ati AbdulWahab, ode kan lawọn mejeeji jọ lọ lọjọ kan, lo ba di pe inu rirun ni Saka n pariwo nigba to de, ẹnu ariwo naa lo si dakẹ si lọsibitu ti wọn gbe e lọ, ti wọn si sin in lọjọ keji nilana ẹsin Musulumi, kawọn eeyan yii too lọọ hu oku rẹ lẹyin naa.
Adajọ Bio Saliu ni ki Fọlọrunṣọ lọọ fẹwọn ọdun mẹrin jura lai si owo itanran, ki baba rẹ si lọọ gbatẹgun oṣu mẹrin lẹwọn, tabi ko sanwo itanran ẹgbẹrun mẹta naira.