Baba Faṣọranti fẹyin ti gẹgẹ bii olori ẹgbẹ Afẹnifẹre

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ẹgbẹ Afẹnifẹre lorilẹ-ede yii ti kede orukọ Baba Ayọ Adebanjọ gẹgẹ bii adele olori ẹgbẹ naa tuntun lẹyin ti Oloye Reuben Faṣọranti to n tukọ ẹgbẹ ọhun tẹlẹ ti kede ipinnu rẹ lati fẹyin ti lẹni ọdun marundinlọgọrun-un.

 

Igbesẹ yii waye ninu ipade oloṣooṣu ẹgbẹ ọhun ti wọn ṣe nile Oloye Faṣọranti to wa niluu Akurẹ, lọsan-an ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

 

Ọba Ọladipọ Ọlaitan, Alaago tí Kajọla Aago, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Atakumọsa, nipinlẹ Ọsun, to jẹ akọwe ẹgbẹ tẹlẹ ni wọn tun yan gẹgẹ bii igbakeji olori.

 

Ọdun 2008 lawọn ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre ti yan Oloye Faṣọranti gẹgẹ bii olori wọn lẹyin iku Oloogbe Abraham Adesanya.

 

Leave a Reply