Baba Ijẹṣa ko ti i kuro lagọọ ọlọpaa o, lọọyaa rẹ lawọn o ni i sanwo tawọn ọlọpaa n beere fun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Loootọ lariwo ayọ gbode kan nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii, pe awọn ọlọpaa ti fun Baba Ijẹṣa, Ọlanrewaju Omiyinka, ni beeli pe ko maa lọ sile. Ṣugbọn titi di ba a ṣe n kọ iroyin yii, ọkunrin naa ṣi wa ni ahaamọ awọn ọlọpaa, wọn ko fi i silẹ rara.

Ohun to fa eyi gẹgẹ bi lọọya rẹ, Amofin Adeṣina Ogunlana, ṣe sọ, ni pe ikọ agbejọro meji ni Baba Ijẹsa ni. O ni oun gẹgẹ bii ẹnikan, sọ fawọn igun agbejọro keji pe ko niidi kawọn sanwo beeli ki wọn too fi onibaara awọn yii silẹ lahaamọ.

O loun jẹ ki wọn mọ pe ọfẹ ni beeli, bi wọn ba si ni ki oniduuro gba beeli afurasi pẹlu iye kan, ko tumọ si pe oniduuro yoo ko owo naa kalẹ, yoo kan wulẹ jẹ ẹni to ni iru owo bẹẹ lọwọ ni.

Lọọya yii sọ pe ṣugbọn awọn igun agbejọro keji yii ko gba bẹẹ, niṣẹ ni wọn n sọ pe afi ki Ijẹṣa sanwo beeli ti yoo fi gba ominira. O ni eyi si lawọn ọlọpaa naa n fẹ.

O tilẹ darukọ ọlọpaa obinrin kan to ni ko fi oju ire wo oun nigba ti ọrọ yii ti bẹrẹ, o ni niṣe lọlọpaa naa taku pe afi ki Ijẹṣa sanwo, kawọn si yẹ foonu rẹ wo lati mọ iye to ni nipamọ kawọn too fi i silẹ.

Eyi lo ni o fa a ti Baba Ijẹṣa ṣe tun wa lahaamọ lẹyin ti kootu Majisreeti ti yọnda rẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i bẹrẹ iṣ gidi. Ilera Baba Ijẹṣa ti wọn lo n mẹhẹ lo fa a ti kootu fi ni ki wọn fun un ni beeli, pe ko lọọ tọju ara ẹ na.

Ṣugbọn awọn ọlọpaa koro oju si ohun ti Lọọya Ogunlana sọ yii, wọn ni ko ri bẹẹ rara. Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko, CSP Muyiwa Adejọbi, ṣalaye pe Baba Ijẹṣa ṣi wa lahaamọ nitori ko ti i ri eto beeli rẹ ṣe pe ni.

O ni irọ buruku ni pe awọn ọlọpaa n beere owo ki wọn too fi ọkunrin onitiata naa silẹ.

‘’A ko beere owo kankan, Ijẹṣa ko ti i ri eto beeli ẹ ṣe pe ni. Nigbakugba to ba ti ri i ṣe tan, a maa fi i silẹ. Nitori naa, ẹnikẹni to ba n sọ pe awọn ọlọpaa da a duro satimọle nitori owo, n fa irun iwaju pọ mọ tipakọ ni’’

Bi eyi ṣe n lọ lọwọ ni atẹjade kan tun jade, ninu eyi ti wọn ti ni Lọọya Adeṣina yii ki i ṣe lọọya Baba Ijẹṣa. Lọọya kan, Ọmọba Kayọde Ọlabiran, sọ pe oun gan-an ni lọọya Baba Ijẹṣa. O ni oun ati obinrin kan torukọ ẹ n jẹ Jane Ogunbiyi ni lọọya Baba Ijẹṣa tootọ, ki i ṣe Adeṣina Ogunlana rara.

Ṣa,Ijẹṣa ṣi wa lahaamọ rẹ to wa, ko ti i foju b’ode

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: