Baba Ijẹṣa ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wa o- Mr LATIN

Nigba ti ọrọ Baba Ijẹṣa yii ko yee tan kiri, to ti di ohun ti wọn n sọ pe o yẹ ki wọn yọ ọ lẹgbẹ ni, ki wọn ma jẹ ko ṣe tiata mọ, ki wọn da sẹria fun un ati bẹẹ bẹẹ lọ, Ọtunba Bọlaji Amuṣan tawọn eeyan mọ si Mista Latin, iyẹn Aarẹ ẹgbẹ TAMPAN ni Naijiria, jade lati ṣalaye ohun tawọn eeyan ko mọ. Eyi lohun ti Latin sọ ninu fidio to ju sori ẹrọ ayelujara.

‘‘Nigba ti ọrọ yii kọkọ ṣẹlẹ, mo paṣẹ fun ẹni to n ṣe akọsilẹ ninu ẹgbẹ TAMPAN pe ko fi atẹjade sita pe a ko fara mọ iwa ti Ijẹṣa hu, a si koro oju si i. Bi wọn ṣe gbe e jade lori atẹ ẹgbẹ wa lemi naa gbe e soju opo mi ki gbogbo aye le ri i.

‘‘Ṣugbọn awọn eeyan tun n pariwo pe o yẹ ka le Baba Ijẹsa kuro ninu ẹgbẹ TAMPAN. Mo fẹẹ fi asiko yii sọ fun yin pe mi o lagbra la ti le Ijẹṣa kuro ninu ẹgbẹ, nitori Ijẹṣa ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN. Ẹni ti ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ mi, agbara wo ni mo ni lati ni ko kuro nibẹ. Oṣere bii temi ni, a jọ n ṣiṣẹ ni. Aimọye ẹgbẹ lo dẹ wa, ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN’

Mista Latin sọ pe ohun ti ẹgbẹ awọn le ṣe naa lawọn ti ṣe yẹn, iyẹn ni gbigbe atẹjade sita pe awọn ko fara mọ iwa to hu, awọn ko si lọwọ si i. O lawọn ko si nidii ki wọn ma fiya jẹ Ijẹṣa, ṣugbọn nigba ti ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oun, ko si kinni kan toun le ṣe si i.

To ba jẹ ọmọ TAMPAN  ni, o ni niṣe lawọn maa kọkọ yọ ọ lẹgbẹ na, ti yoo jiya to tun tọ si i labẹ ofin pẹlu. Ṣugbọn ni ti Ijẹṣa yii, Aarẹ TAMPAN ni ko si kinni kan toun le ṣe si i.

Leave a Reply