Baba Ijẹṣa ko fipa ba ọmọ ọdun merinla lọ pọ, o kan fọwọ pa a lara lasan ni-Ọlọpaa

Bi gbogbo nnkan ba lọ bo ṣe yẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa sọ pe o ṣee ṣe ki awọn da oṣere ilẹ wa to ti wa lakata wọn ti wọn mu fun ẹsun ifipa ba ni lo pọ, Ọlanrewaju James Omiyinka ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijẹṣa silẹ. Eyi ko sẹyin bi ileeṣẹ eto idajọ ilẹ wa ṣe wa lẹnu iyanṣẹlodi, eyi ti ko ni i fawọn lanfaani lati gbe e lọ sile-ẹjọ. Niwọn igba ti awọn ko si ti lanfaani lati tọju rẹ sọdọ fun ọjọ gbọgbọrọ bẹẹ labẹ ofin, o di dandan ki awọn gba beeli rẹ, ko maa lọ sile.

Bo tilẹ jẹ pe Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Muyiwa Adejọbi, ti kọkọ sọ pe awọn ri i pe loootọ ni Baba Ijẹṣa ṣe ọmọbinrin naa niṣekuṣe nigba ti wọn kọkọ mu un ni ọjọ Iṣẹgun to kọja, ṣugbọn ni bayii, agbẹnusọ naa sọ pe Baba Ijẹṣa ko ba ọmọ naa lo pọ, o kan fọwọ pa a lara ni ninu ẹrọ aṣofofo to yaworan naa. Niwọn igba ti ẹri ibalopọ ko ti waye, awọn ko le sọ pe o fipa ba a lo pọ.

Bakan naa ni wọn sọ pe ẹsun fifipa ba ọmọ naa lo pọ lọdun meje sẹyin ko ṣee tẹle, nitori awọn obi ọmọ yii ko waa fi to awọn leti lasiko naa.

Leave a Reply