Baba Ijẹsa ko gbadun rara lahaamọ to wa, o ti ru, ko lokun mọ rara, bẹẹ lo n tiro rin-Lọọya

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Iroyin to ti atimọle ti Baba Ijẹṣa, Ọlanrewaju Omiyinka, wa jade ko daa. Lọọya rẹ, Amofin Adeṣina Ogunlana, sọ pe agara ti da ọkunrin naa lahaamọ. O lo ti ru, bẹẹ ni ko si le rin daadaa mọ, niṣe lo n tiro, ko si ni okun ninu rara.

Ninu lẹta kan ti lọọya yii kọ si Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, lo ti sọ eyi di mimọ lọjọ Ẹti to kọja.

Idasilẹ Baba Ijẹṣa ni lọọya rẹ n beere fun to fi ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ si onibaara rẹ yii lahaamọ ti wọn fi i si latigba ti ọrọ afipa-ba-ọmọde lo pọ ti bẹrẹ.

Lọọya Ogunlana  ṣalaye ninu lẹta naa pe, ‘‘Bi ẹ ṣe ti Ọgbẹni Ọlanrewaju James mọle lati ọjọ yii to si ti fẹrẹ pe ọgbọn ọjọ to ti wa nibẹ ta ko ẹtọ rẹ labẹ ofin ilẹ wa ti wọn ṣe lọdun 2019.

‘’Nigba ti mo ri i pẹlu Yọmi Fabiyi, ọkan rẹ ko balẹ, o ti ru, ko si le fi ẹsẹ otun rẹ rin daadaa mọ, niṣe lo n tiro. Mo fẹẹ fi da yin loju pe Omiyinka ko le sa lọ, o ti ṣetan lati jẹjọ rẹ’

Bi apa kan lẹta naa ti ka niyẹn.

Ẹ oo ranti pe ọpọlọpọ ipe lo ti wa, pe kawọn ọlọpaa Panti to ti Baba Ijẹṣa mọle, tu u silẹ na, nitori ẹṣẹ to ṣẹ ko kọja beeli.

Ati pe kootu ti wọn fẹẹ gbe e lọ ni ko ṣiṣẹ yii, awọn lọọya rẹ, Yọmi Fabiyi atawọn ololufẹ ọkunrin naa, sọ pe titẹ-ẹtọ-ẹni loju mọlẹ lawọn ọlọpaa n ṣe yii, wọn lo yẹ ki wọn fi i silẹ na bi ofin ṣe sọ ni.

Ṣugbọn awọn ọlọpaa lawọn ko le fi ọkunrin onitiata naa silẹ bẹẹ, nitori imọran to ti ọdọ DPP to n gba kootu nimọran wa, ko sọ pe kawọn fi i silẹ na, wọn ni ahamọ ti wọn ni ko wa lawọn fi i si yẹn.

 

 

Leave a Reply