Baba Lẹgbaa onitiata ti ku o

Ọkan ninu awọn agba oṣẹre lagboole tiata Yoruba, Alaaji Yẹkini Oyedele tawọn eeyan mọ si Baba Lẹgba ti papoda laaarọ oni, Mọnde, ọjọ keje, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020.

Ile mọlẹbi baba naa to wa n’Itoku, niluu Abẹokuta ni agba oṣere naa dakẹ si, oni yii naa ni wọn yoo si gbe e wọ kaa ilẹ lọ gẹgẹ bii Musulumi ododo.

Ọjọ pẹ to ti rẹ Baba Lẹgba,bo tilẹ jẹ pe aarẹ agba ni. Asiko kan wa ti ẹsẹ n dun baba yii, bẹẹ si ni awọn eeyan ti fi igba kan dawo fun un lati tọju ara ẹ.

Lasiko ti Korona gbilẹ gidi, ti konilegbele si wa, ni iya kan to ni oun le ta oju ara oun jẹun, lọọ fun Baba Lẹgbaa lowo nigba toun naa ri aanu gba lọwọ awọn eeyan. Ṣugbọn ko too digba yẹn lawọn eeyan kọọkan ti nawọ oore si Alaaji Oyedele, ti wọn ni ki wọn maa ri nnkan tọju ara wọn.

Awọn agba oṣere bii Oloogbe Akin Ogungbe, Oloye Charles Olumọ(Agbako) atawọn mi-in ni wọn jọ kopa pupọ ninu ere ori itage Yoruba, nigba ti aye ko ti i di ti onifiimu agbelewo

About admin

Check Also

Nitori to ni oun yoo fopin si eto aabo ni Borno ati Yobe, PDP Ekiti sọrọ si Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde …

2 comments

  1. Ki Olorun Oba fi orun ke baba legba ki o tewon si afefe rere
    Awon ololufe tiata gbadun won gan- an nigba ti won nse ere tiata need gba aye won
    Ki Oluwa tuu awon ebi won lara amin

  2. Haaaaa baba oninu re lo

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: