Baba mi kọ lo n da Naijiria ru, awọn to ko ounjẹ COVID pamọ ni-Ọmọ Buhari

Jide Kazeem

Ọkan lara awọn ọmọ Aarẹ orilẹ-ede yii, Arabinrin Zahra Buhari-Indimi, ti kilọ fawọn ọmọ Naijiria pe ẹnikeni ko gbọdọ sọrọ odi si baba oun mọ, nitori oun gan-an kọ ni iṣoro Naijiria, bi ko ṣe awọn to n ko ounjẹ ti wọn pese fun COVID-19 to wa fun awọn araalu pamọ.

Lori ikanni Instagiraamu lo kọ ọ si pe, ‘‘Ni bayii tawọn ọmọ Naijiria ti ri i pe niṣe lawọn oloṣelu kan ko ounjẹ iranwọ ti Buhari ko fun wọn lasiko isemọle koronafairọọsi pamọ si yara wọn, niṣe lo yẹ ko ye wọn bayii pe baba naa ki i ṣe ọta wọn rara.

O fi kun un pe ohun itiju lo yẹ ko jẹ fun awọn ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori, ati pe asiko niyi fawọn to n sọ ọ kiri pe Buhari ko ṣejọba daadaa lati sinmi ẹnu wọn.

Tẹ o ba gbagbe, kaakiri awọn ipinlẹ nilẹ Yoruba, titi de ilẹ Ibo ati ọdọ awọn Hausa paapaa ni awọn eeyan ti n ja ibi iko-ounjẹ pamọ si, ti wọn si n ko wọn kẹtikẹti lọ sile wọn.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe, wọn tun ba awọn ounjẹ ọhun nile ẹlomi-in paapaa.

Leave a Reply